Oyo NLC: A kò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì láti d'ẹ́rù ba ìjọba tuntun

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọyọ, NLC, ti so iyanṣẹlodi rẹ rọ.
Lasiko to n kede igbesẹ naa, Alaga ẹgbẹ NLC nipinlẹ Ọyọ, Comrade Bayọ Titilọla-Sodo, sọ pe awọn bẹrẹ iyanṣẹlodi pẹlu ireti pe ọjọ diẹ to ku ninu iṣejọba to wa nita lọwọlọwọ nipinlẹ Ọyọ yoo so eso rere fun awọn oṣiṣẹ.
O ni kii ṣe ọna tabi erongba lati dẹru ba ijọba to n bọ.
Lara awọn ohun to fa a ti awọn oṣiṣẹ naa fi yanṣẹlodi gẹgẹ bi Titilọla-Sodo ṣe sọ ni ajẹsilẹ owo oṣu ati owo ifẹhinti awọn oṣiṣẹ fẹhinti, eyi toto ọgọta billiọnu Naira.
Bakan naa ni fifi opin si aṣẹ ti ko jẹ ki wọn o gbe awọn oṣiṣẹ lati ibikan si omii, gbigba awọn oṣiṣẹ ti wsn da duro lọna aitọ pada, ajẹsilẹ owo oṣu awọn olukọ ileewe alakọbẹrẹ ati awsn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ kan.
O wa kesi gomina tuntun fun ipinlẹ Ọyọ, Onimọ Erọ Seyi Makinde, pe ko ma ṣe yi ohùn pada lori awọn ileri to ṣe lasiko to n polongo ibo.
Ọjọ Ẹti to kọja ni ẹgbẹ oṣiṣẹ naa bẹrẹ iyanṣẹlodi.











