Osun tribunal: Ta ni ilé ẹjọ́ yóò gbẹ́ adé ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun fún?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nibi idajọ ileeẹjọ to n gbọ ẹjọ idibo gomina nipinlẹ Ọṣun, igbimọ idajọ naa ni oun yoo yọ ibo ẹgbẹrun meji o le mọkandinlogun ninu ibo APC ati ẹgbẹrun kan o le igba ati mẹrindinlaadọta ninu ibo PDP lawọn ibudo idibo mẹtadinlogun ti wọn ko ti tẹle ilana idibo lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni ile ẹjọ naa tun ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu PDP kuna lati fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni ibo adile waye lawọn ibudo idibo marundinlaadoje.
Iléeṣẹ́ APC, PDP dá páropáro ṣáájú ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun

Paroparo ni ọ́fíìsì ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP dá ní Ìpínlẹ̀ Ọṣun ní bí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú méjèèjì náà ṣe ń dúró de ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ń rí sí èṣùn tó súyọ lórí èsì ìbò gómìnà Ìpínlẹ̀ náà tó wáyé lọ́dún 2018
Lọwọ yii, idajọ ṣi n lọ lọwọ ni ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ naa nilu Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lónìí nilé ẹjọ́ yóò dá ẹjọ́ ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun
Ṣe wọn ni irawe kan ko ni dajọ ilẹ ko sunna. Loni ọjọ ẹti, ọjọ kejilelogun oṣu kẹta ọdun 2019 ni ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun to suyọ lori idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ọṣun yoo gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹni gan an to bori idibo naa.
Ni ọjọ kejilelogun oṣu kẹsan ọdun 2018 ni eto idibo ati yan gomina fun ipinlẹ Ọṣun waye. Bi o tilẹ jẹ wi pe ajọ INEC to n ṣe agbatẹru eto idibo lorilẹede Naijiria ko lee fi ẹnu idibo naa jona sojukan naa lọjọ naa, nibi ti oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Ademọla Adeleke ti n lewaju; eto atundi ibo waye lawọn ẹkun idibo melo kan ni ọjọ diẹ si idibo naa lo yi ohun gbogbo pada ti oludije APC, Gboyega Oyetọla si wa bori lẹyin ajọṣepọ to waye laaarin ẹgbẹ oṣelu APC ati gbajugbaja oloṣelu ni, Iyiọla Omiṣore ti oun pẹlu jẹ oludije ni abala akọkọ idibo naa.

Oríṣun àwòrán, @IsiakaAdeleke1
Ni bayii, ajọ INEC ti kede Gboyega Oyetọla gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun, wọn si ti bura fun un wọle gẹgẹ bii gomina lati oṣu kọkanla ọdun 2018.
Amọṣa, oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP, Ademọla Adeleke ti gba ile ẹjọ lọ pẹlu awijare pe oun ni o bori atipe ka yọwọ awọn iwa aitọ to sọ pe o waye lasiko idibo naa kuro, oun lo yẹ ki ajọ INEC kede gẹgẹ bii gomina.
Ile ẹjọ to n gbọ ẹhonu idibo naa bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu bi o tilẹ jẹ pe ọpọ awuyewuye lo kọkọ waye lori rẹ, ki o to di pe o gbe ijoko rẹ lọ si olu ilu ilẹ Naijiria, Abuja.

Oríṣun àwòrán, @raufaregbesola
Ni bayii ti idajọ yoo waye loni, igun mejeeji lo ti n fọwọ sọya pe lọdọ awọn ni ọsan didun yoo so si lori idajọ naa.
Adura ati awẹ, titi kan ipade adura ita gbangba ni awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji, APC ati PDP ṣe ṣaaju idajọ ti yoo waye loni.
Amọṣa, ilẹkẹ maa ja sile, maa ja sita, ibi kan naa ni yoo jasi. Ẹyin ẹ tẹti leko o lori bi o ba ṣe n lọ ni ile ẹjọ naa loni.












