Nigerian 2019 Elections: Àwọn wo ni ọ̀rẹ́ Atiku tó fẹ́ sọ di olówó tó bá di ààrẹ?

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, @Atiku

Lasiko ti eto idibo ba n kanlẹkun, oriṣiriṣi ileri ni awọn oloṣelu maa n ṣe fun awọn araalu.

Ọpọlọpọ awọn ileri tabi ọrọ ti wọn ba sọ yii lo maa n saba fa awuyewuye laarin awọn oludibo, nitori ọpọ maa n beere pe ọna wo ni wọn fẹ gbe e gba lati mu u ṣẹ.

Atiku Abubakar ninu ọrọ to sọ lasiko to kopa nibi eto kan ti wọn fi sori riro eto ọrọ aje Naijiria lagbara to waye pẹlu awọn oniṣowo nilu Eko.

Eto naa ti ileeṣẹ amohunmaworan Channels ṣafihan rẹ, ni fidio ọhun ti Atiku sọ ti n fa ariyanjiyan lori ayelujara.

Atiku sọ pe oun ko ni sọ awọn mọlẹbi oun di olowo, bi ko ṣe awọn ọrẹ oun bi o ba fi le di aarẹ Naijiria, pẹlu ibeere ti o beere pe ṣe ko tọ ki awọn ọrẹ oun o di olowo ni?

Eyi si ti n fa awuyewuye laarin awọn ọmọ orilẹede Naijiria, ti ọpọlọpọ n beere pe awọn wo gan an ni ọrẹ Atiku? Ati pe ọna wo lo fẹ fi sọ wọn di olowo, niwọn igba ti ko ba ti ni ọwọ iwa ibajẹ ninu.

Ọpọlọpọ ọmọ orilẹede Naijria lo si ti n beere wi pe awọn wo ni ọrẹ Atiku? Ati pe ọna wo lo fẹ gba sọ wọn di olowo?

Ọpọ tilẹ n tọka si bo ṣe sọ pe oun yoo sọ ileeṣẹ epo rọbi Naijiria, NNPC, di ti aladani, pe ṣe awọn ọrẹ rẹ l'oun gbero lati ta a fun.

Nibi eto naa ni Atiku ti sọ pe oun yoo sọ ileeṣẹ NNPC di aladani, koda 'bi yoo ba gba ẹmi oun.'

Ẹwẹ, awọn kan ni igbagbọ pe ọrọ ti Atiku sọ yii fihan pe awọn to jẹ 'ọrẹ' rẹ nikan ni ijọba rẹ yoo gbe, ti yoo si sọ gbogbo ọmọ Naijria to ku di talaka.

Ṣugbọn, bi awọn kan ṣe n bu ẹnu ẹtẹ lu ọrọ ti Atiku sọ, ni awọn kan n sọ pe igbesẹ to tọ ni lati sọ ileeṣẹ NNPC di ti aladani. Awọn to sọ bẹ ẹ woye pe ṣiṣe bẹẹ yoo mu opin de ba 'iwa ibajẹ to wọpọ ninu ajọ naa.'