ASUU strike : Ìdí tí àwọn olùkọ́ kò ṣe tíì f'òpin sí ìyanṣẹ́lódì

Oríṣun àwòrán, Frédéric Soltan
Ijọba orileede Naijiria ti kede pe awọn ti yanju awọn olukọni ile ẹkọ fasiti ti wọn gun le iyanṣẹlodi.
Ikede naa waye lẹyin ipade kan ti wọn ba awọn olukọ naa ṣe lọjọ Aje.
Minisita fun ọrọ igbanisiṣẹ, Chris Ngige to kede ọrọ yi fun awọn akọroyin sọ pe ijọba ti buwọlu sisan owo to le ni biliọnu mẹẹdogun fun atunṣe awọn ile ẹkọ fasiti ati wi pe Aarẹ Buhari ti ni ki wọn san ogun biliọnu naira fun sisan owo oṣu ti ijọba jẹ awọn olukọ naa lati ọdun 2009 si 2012.
Aarẹ ẹgbẹ awọn olukọ ni fasiti Naijiria, Biọdun Ogunyẹmi ti oun naa wa nibi ipade naa sọ wi pe igbimọ alaṣẹ́ ẹgbẹ naa yoo ṣe ipade lati ṣe agbeyẹwo nnkan ti ijọba sọ.
Biodun ni lyin ipade yi ni awọn yoo sọ boya iyanṣẹlodi yoo tẹsiwaju si tabi yoo dopin.
Gẹgẹ bi oun to sọ, awọn nkankan ṣẹku tawọn yoo jiroro le lori ki wọn to le so iyanṣẹlodi naa to bẹrẹ lọjọ kẹrin ọdun 2018 rọ.








