Ilé Asòfin: Buhari kò fi asojú South-South, South-East sínú olùdarí EFCC

Oríṣun àwòrán, Twitter/The Seante
Ede-aiyede bẹ silẹ nile aṣofin agba l'Abuja lọjọ Iṣẹgun lori orukọ awọn eeyan mẹrin ti Aarẹ Muhammadu Buhari fi sọwọ fun igbimọ oludari ajọ EFCC.
Awọn sẹnẹtọ to n ṣoju apa ila oorun guusu (South East) ati awọn to ṣoju apa aarin gbungbun guusu ( South South) yari, wọn ni ko si ẹnikan lati agbegbe awọn ninu awọn ti aarẹ yan sipo.
Ṣugbọn awọn sẹnẹtọ lati apa ariwa orileẹde Naijiria, ti wọn tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ki ile tẹsiwaju lati buwọlu orukọ awọn ti Aarẹ Buhari fi ranṣẹ sile.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Orukọ awọn mẹrin naa ni Ndasule Moses lati aarin gbungbun ariwa, Lawan Mamman lati ila oorun ariwa, Gladanci Imam Najip lati iwọ oorun ariwa ati Adeleke Adebayo lati iwọ oorun guusu.
Lai beṣu bẹgba, ni igbimọ ile to wa fun igbogun tiwa ajẹbanu ati siṣe owo ilu kumọkumọ labẹ alaga Chukwuka Utazi ti sọ pe, ki ile ṣe apero lori iyansipo naa lati ọdọ aarẹ.
Ṣugbọn ariyanjiyan bẹ silẹ, ti awọn sẹnẹtọ kan si dide si ara wọn. Akitiyan aarẹ ile, Bukọla Saraki lati dawọn lẹkun si lo ja si pabo.
Eleyi lo mu ki awọn aṣofin ṣe ipade idakọnkọ, lẹyin ipade yii ni wọn jọ gba lati so apero rọ lori ọrọ naa.









