2019 Election: Ta ni olùdíje gómìnà l‘Ogun, Kashamu àbí Adebutu?

Buruji Kashamu

Oríṣun àwòrán, @Sen_Kashamu

Omi alaafia ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Ogun lo ti n daru logbologbo bayii, ti awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa si ti pin si meji.

Awọn ọmọ ẹgbẹ PDP kan ti to sẹyin Ọladipupọ Adebutu, ti olu ile ẹgbẹ ni Abuja fi ontẹ lu pe oun ni oludije ẹgbẹ to kajuẹ, bẹẹni wọn ti gbe asia ẹgbẹ le lọwọ.

Amọ lọwọ-lọwọ bayii, ajọ eleto idibo nilẹ wa, INEC, ti kede pe, Adebutu kọ ni oun mọ bii ojulowo oludije fun ipo gomina ni ipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oselu PDP bikose Sẹnetọ Buruji Kashamu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Igun OPC: OPC ti sọnù, àwọn èèyàn ń sá fún wa láì fẹ́ darapọ̀ mọ́ wa

Lẹyin ọjọ mẹta ti alaga ẹgbẹ PDP ni Naijiria, Uche Secondus si ti gbe asia ẹgbẹ le Adebutu lọwọ, igun ti Kashamu ti se ifilọlẹ eto ipolongo ibo rẹ nilu Ijẹbu Igbo.

Nibi ayẹyẹ ifillẹ eto ipolongo ibo naa, alaga ẹgbẹ PDP to ko igun Kashamu sodi, Bayọ Dayọ ni igun tawọn ni ojulowo PDP ti ofin ti lẹyin , ti ajọ eleto idibo si damọ.

Nigba to n ba ipejọpọ ero sọrọ ipolongo ibo naa, ti wọn gbe sori mohun-maworan bo se n lọ lọwọ, Buruji Kashamu seleri pe ijọba to nifẹ mẹkunnu ni oun yoo se.

Buruji Kashamu laarin awọn ero

Oríṣun àwòrán, @Sen_Kashamu

O ni oun ti n ran mẹkunnu lọwọ tẹlẹ, amọ ti oun ba di gomina, anfaani yoo tubọ wa fun oun lati ran awọn eeyan ti ori n ta lẹru.

Nigba to n gbe asia ẹgbẹ fun Kashamu, Bayọ Dayọ ni Buruji ni Awolọwọ asiko yii, ti ajọ Inec si ti tẹwọ gbaa.

Amọ nigba to n fesi si isẹlẹ yii, agbẹnusọ fun ẹgbẹ PDP lapapọ, Kọla Ọlọgbọndiyan ninu atẹjade kan ni , ipolongo ibo arumọjẹ ni Kashamu se, o ya ero lo ni, ayederu asia ẹgbẹ si ni wọn gbe fun.