Fake News:Iwadii BBC lori ayederu iroyin ati bo ṣe dakun wahala to bẹ silẹ ni Igangan
Laasigbo to waye laarin awọn Fulani ati Yoruba ni ilu Igangan jẹ eleyi ti ọpọ ko ni gbagbe .
Ohun to si mu ki ọrọ yi ri bẹ ni pe pupọ ẹmi lo ba iṣẹlẹ naa lọ ti aimọye dukia naa si ṣofo.
Bi ere bi ere ni kini naa bẹrẹ amọ lẹyin ọdun kan kọja diẹ ti o waye, BBC foju inu ati iwadii wo nkan to ṣẹlẹ gaan to mu laasigbo yi wa.
Ninu iwadii wa, a ribi tan imọlẹ si awọn iṣẹlẹ kan ati bi wọn ṣe lamilaaka lori wahala to waye ni.
Ati eyi to ṣe ootọ ati awọn ti o jina diẹ sootọ la gbe yẹwo.
Ẹkunrẹrẹ binkan ti ṣe lọ wa ninu fido ti a ṣe agbekalẹ rẹ yi.




