Yolywood: Ìgbéyàwó Cute Abiola, Woli Arole, Lateef Adedimeji, Mo bimpe, Yetunde Barnabas, Peter Olayinka àti Toyin Lawani gọntíọ

Orisiirisi igbeyawo lo wa laye atijo ati laye ode oni.

Awon igbesẹ kọọkan pa awọn mejeeji papọ ni eyi ti iran Yoruba fi nilo ọkunrin ati obinrin.

Bẹẹ ọmọ ti aye bi ni aye n pọn.

Ọpọ igbeyawo ni o ti lu ori ayelujara pa ti awọn eeyan si n sọrọ nipa wọn.

Akojopọ marun un nibẹ ni BBC ṣa jọ ti o jẹ igbeyawo laarin awọn oju oge Yollywood.

Wo àwọn ìgbéyàwó tí ayé pariwo wọ́n nigba ti wọn waye laipẹ:

1. Lateef Adedimeji & Mo'Bimpe

Igbeyawo laarin oṣere Yoruba meji ti ololufẹ wọn si n pariwo kiri lori ayelujara pe eyi gọntiọ.

Awọn naa ni Oladimeji Abdulateef ati Adebimpe Oyebade.

Ojọ kejilelogun, oṣu kejila, iyẹn oṣu to kọja ni igbeyawo naa waye.

Die lara awọn to peju pesẹ sibi igbeyawo Lateef ati Mo Bimpe naa ni awọn oṣere bii: Toyin Abraham, Kolawole Adeyemi, Nkechi Blessing Sunday, Mercy Aigbe, Adunni Ade, Wumi Toriola, Femi Adebayo, Yetunde Bakare, Odunlade Adekola ati awọn mii.

Ọpọlọpọ eto nipa igbeyawo naa lo kun ori ayelujara.

2. Toyin Lawani & Segun Wealth:

Lọjọ kejila, oṣu kẹfa ọdun to lọ ni ọjọ malegbagbe ninu aye akọṣẹmọṣẹ yeye oge arẹwa ni, Toyin Lawani ati ololufẹ rẹ Segun Wealth.

Ipinlẹ Eko ni igbeyawo naa ti waye nibi ti awọn eekan ilu ti wa sibẹ.

Ọ̀pọ̀ awọn ololufẹ rẹ to jẹ gbajumọ lawujo ti wọn fi iwe pe lo peju pese sibi ayẹyẹ naa.

Oriṣiirisi aworan lo lu ayelujara pa lasiko igbeyawo Toyin Lawani ati Segun Wealth ti aye fi n pariwo.

3. Yetunde Barnabas & Peter Olayinka

Oserebinrin ni Yetunde Barnabas lo gab oruka lọwọ ololufẹ nibi isopọ wọn loṣu kẹfa ọdun to lọ.

Bayii won ti pe oṣe mẹfa ninu igbeyawo.

Yetunde ati gbajugbaja agbabọọlu ikọ Super Eagles ni, Olayinka Peter ni won jọ di tọkọtaya.

Ọpọ oju awọn elere idaraya paapaa awọn agbabọọlu lo kun inawo naa pẹlu awon osere lọkunrin ati lobinrin.

Iroyin ni ọdun meji ni wọn fi kọkọ fẹ ara wọn sọna ṣaaju igbeyawo naa.

4. Wolii Arole ati Yemi:

Igbeywao alarinrin waye larin gbajugbaja adẹrin poṣonu omọ Ogbomoso nii ti ọpọ n pe ni Wolii Arole.

Toyin Balogun lo gbe ololufẹ rẹ Yemi ni iyawo lọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin, lọdun to kọja.

Ojọ naa jẹ ara ọtọ fun Wolii Arole ati Yemi to dun debi wi pe o gba ọkọ ayọkẹlẹ gẹgẹ bii ẹbun igbeyawo lọjọ naa.

Won ṣe idana pẹlu igbeyawo alarede nile ijọsin ni.

5. Cute Abiola ati Oloufe re, Kudirat Mosunmola:

Aderinpoṣonu ti o gbajumọ pupọ lori ayelujara Instagram ni, Cute Abiola naa ti ṣe igbeyawo.

Cute Abiola to tun jẹ ọmọ ogun ori omi ni Naijiria naa fẹ ololufẹ rẹ ni ilu Ogbomoso ni ipinlẹ Oyo lọọ ẹti, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu karun un lọdun to kọja.