Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade sọ bi ìrìnàjò ìfẹ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ láàrin wọn

Kii se iroyin tuntun mọ, pe gbajugbaja osere meji, Lateef Adedimeji ati Adebimpe Oyebade, yoo ṣe igbeyawo laipẹ.

Amọ, bawo ni ifẹ wọn ṣe bẹ̀rẹ̀?

O ti to asiko diẹ, koda yoo ti to ọdun meji ti iroyin ti n jade pe awọn mejeeji n fẹ ara wọn, botilẹ jẹ pe wọn jiyàn rẹ.

Ninu ọrọ ti wọn sọ fun itakun agbaye igbeyawo, Bella Naija, tọkọtaya naa sọ pe akọsilẹ Ọlọ́run ni ọrọ ifẹ wọn.

Ibi isẹ tiata kan ni àwọn mejeeji ti kọkọ pade lati jọ ṣisẹ pọ. Kii si ṣe loju ẹsẹ ni irinajo ifẹ bẹ̀rẹ̀ ni aarin wọn.

Wọn ti pade ni àìmọye igba saaju asiko ti isẹ pa wọn pọ ni ọdun 2018, sugbọn wọn o ba ara wọn sọrọ.

Ẹnikan lara wọn lo kọkọ yo ìfẹ́ fun ẹnikeji, àmọ́ ko sọrọ.

Lasiko ti a sọ yii, àwọn mejeeji wa ninu irinajo ifẹ pẹlu ẹlomiran, ti wọn si n la isoro kọja ninu rẹ.

Ṣugbọn, ọrẹ timọtimọ ti ẹni kankan ko le ri idi rẹ ni wọn.

Lojoojumọ ni isẹ sinima n pa wọn pọ. Ọrẹ wọn lágbára debi pe awọn akọroyin n fi wọn ṣe iroyin lojoojumọ.

Adebimpe ko tete gba 'lẹta ifẹ' Lateef, nitori pe ko tii ri àmì pe ọkọ rẹ ni.

Ṣugbọn lọjọ kan, o ri àmì.

Nibi isẹ sinima IGE, ti Toyin Abraham kọ, ni wọn wa, ti Adebimpe ti ri àmì to n wa ninu oju Lateef. Gẹgẹ ṣe gẹgẹ wayi. Otutu ifẹ bo Bimpe.

Bẹẹni wọn bẹ̀rẹ̀ irinajo ifẹ wọn titi Lateef fi fun ni oruka adehun igbeyawo.

Ọjọ́ kejilelogun, osu Kejila, ọdun 2021 ni wọn o di tọkọtaya.