Yollywood: Ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi kò rọrùn rárá ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ pé mó di ayaba- Jaye Kuti

Gbajugbaja osere binrin Jayeola Kuti fi imoore han lori ibi ti Oba Oke ti gbori ẹ soke de.

Jaye Kuti fi ọrọ yii lede loju opo Instagram ẹ nibi to ti fi ki ara rẹ ku oriire.

Jaye Kuti sọrọ lori bi ibẹrẹ aye rẹ ṣe ri ti nkan ko rọgbọ rara.

O mẹnuba awọn idaamu to ti da ọkan rẹ ru tẹlẹ nibẹrẹ bo ṣe maa n ri fun ọpọlọpọ eeyan laye.

Arabinrin Jaye Oluwakemi Kuti to jẹ olootu ati ogbontarigi oṣere yii ni oun n dupe lọwọ Olorun Oba to da oun si di asiko yii.

Omo bibi ipinlẹ Ogun ni Jaye Kuti jẹ.

Ojọ kéwaa, oṣu keje ni a bii. Ikorodu Grammar School nile ẹkọ to ti kawe girama.

Jaye kẹkọọ nipa iṣẹ akọwe ni ile ẹkọ Gbogbonise ijọba apapọ to wa ni Ilaro ipinlẹ Ogun.

Bakan naa ni Jaye Kuti kẹkọọ nipa imọ ede oyinbo ni Fasiti ijọba apapo to wa ni Akoka nipinlẹ Eko.

Lọdun 2012 ni ere ori amohunmaworan : Laff Patterns gbe e jade

Jaye Kuti ni: Ijo Ope mi da ? Ijo Ope mi re…Gbogbo ara mi o mafi gbe Jesu mi ga Blessed be God Almighty!