You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Downing Street parties: Boris Johnson takú pé òun kò lọ b'awọn aṣòfin ṣé n retí àbọ̀ ìgbìmọ̀ Susan Gray
Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi Boris Johnson ti n leri leka pe oun ko ni fi ipo silẹ, bi awọn aṣofin ṣe ni ko fipo silẹ lori sun pe o se apejẹ lasiko iṣede Covid-19.
Awọn aṣofin ṣi n duro de abajade iwadii igbimọ Susan Gray ti wọn ti n reti lati ana.
Lasiko ti wọn n beere ọrọ lọwọ rẹ alagba Keir Stamer kesi olootu ijọba lati mu ileri rẹ to se pe oun yoo kede esi iwadii yi lẹkunrẹrẹ.
Boris Johnson fesi pada pe oun yoo ''ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe sọ''
Ile ijọba sọ pe awọn lero lati kede esi yi gẹgẹ bi wọn ba ti se gbe le olootu lọwọ.
Iroyin to tẹ BBC lọwọ ni pe arabinrin Gray ti pari iwadii naa ṣugbọn o ku ki wọn fi ranṣẹ si olootu ijọba
O jọ pe awọn aṣofin yoo ni lati ṣe suuru di tabi kọja Ọjọbọ ki wọn to foju ba esi iwadii yi.
Ọgbẹni Johnson ti sọ pe oun yoo faaye silẹ fawọn ẹgbẹ alatako lati ṣayẹwo iwadii naa koun to fesi le lori.
Ẹwẹ ileeṣẹ ọlọpaa Metropolitan ti sọ pe awọn ti bẹ iwadii lori ẹsun pe wọn tapa si ofin iṣede lasiko Covid-19 ni ile ijọba.
Igbimọ Sue Gray lo fi ẹri ṣọwọ si wọn pe iru nkan bayi waye ni Downing Street.
Nibi ijiroro ile to gbọna laala,aṣofin Kier sọ pe olootu ijọba ti ṣaaju sọ fawọn pe ''gbogbo ilana lawọn tẹlẹ'' ni ile ijọba Downing Street lori apejọ lasiko iṣede Covid-19.
Olori ẹgbẹ Labour fi kun pe ''Nigba to ti wa fnu ara rẹ jeri si ilana to de awọn olootu ijọba eyi to tako ki wọn parọ fawọn aṣofin, se yoo wa kọwe fipo silẹ?''
Esi ti Ọgbẹni Johnson da pada ni pe''Rara''
O fẹsun kan Keir pe o n wa ọna lati dẹyẹ si oun ni toun ti pe gbogbo ohun to yẹ loun tẹlẹ.
Olori ile aṣofin Lindsay Hoyle pada ni lati maa da si aarin wọn aṣofin koda o halẹ mọ wọn pe oun yoo le wọn kuro nile aṣofin.
Wọn fa ọrọ yi titi ni ile ti arakunrin Johnson si pada sọ pe ''a ni lati fi ọrọ silẹ titi di igba ti abajade iwadii igbimọ, se o kuku mọ pe bi ọwọ mi ba tẹ, ohun ti mo ni maa ṣe naa ni mo maa ṣe''
Apejẹ ọjọ ibi
Iroyin nipa apejẹ ọjọ ibi ti wọn ṣe fun ọgbẹni Johnson naa ti jẹyọ lọsẹ yi.
Awọn ọmọ ẹgb oṣelu Tory kan ti pe fun ikọwefiposilẹ Johnson ṣugbọn ọpọ ni awọn yoo duro de esi iwadii Gray ki wọn to kọwe beere ifiposilẹ rẹ.
O kere tan mẹrinlelaadọta awọn yi lo ti kesi aṣofin Graham Brady,alaga igbimọ awọn to n joko sẹyin nilẹ, lati ṣe agbekal idibo lori ọrọ olootu ijọba.
Lọwọ bayi bi wọn ba dibo pe awn dunnu si aṣofin wọn ko tun le dibo mii mọ ayafi ti oṣu mejila ba pe
Igbimọ ile lawọn ko gbero lati mu iyipada ba ofin yi lati le faaye gba idibo meji lori olootu toun ti pe a ti n gbọ fifinfin pe wọn gbero lati ṣe bẹ.