You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Covid-19: Àwọn nǹkan mẹ́ta tí a kò tíì mọ̀ nípa Covid-19 lẹ́yìn tí àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ rèé
Inu oṣu kejila, ọdun 2019 ni arun SARS-CoV-2, ti ọpọ mọ si Covid-19, tabi Coronavirus bu jade niluu Wuhan, lorilẹ-ede China.
Lati ọdun naa lọhun, ko din ni miliọnu lọna ọọdunrun ati aadọta eeyan to ri fara kasa arun naa kaakiri agbaye, nigba ti nnkan bii miliọnu marun un eeyan ti ba arun naa lọ.
Oniruru akitiyan lawọn onimọ sayẹnsi ti ṣe lati le koju arun naa, lara rẹ si ni bi wọn ṣe po abẹrẹ ajẹsara fun arun ọhun laarin ọdun meji to bẹ silẹ.
Yatọ si abẹrẹ ajẹsara, awọn onimọ ijinlẹ tun ti ṣawari awọn oogun kan to lagbara lati koju arun ọhun, eyii to mu ki ọpọ awọn to ti ni arun naa pada sile wọn layọ ati alaafia.
Ẹwẹ, awọn onimọ ti wa sọ pe arun naa le ma kasẹ kuro nilẹ patapa lai ṣe pe wọn ri idahun si awọn ibeere mẹta kan.
Awọn ibere naa ree.
Nibo ni arun naa ti wa?
Ileeṣẹ kan to n ri si eto ilera nilẹ Gẹẹsi kede loju opo itakun agbaye rẹ pe awọn ko tii le sọ ni pato orisun ibi arun naa ti ṣẹyọ.
Ninu oṣu Keji, ọdun 2021, ikọ WHO to n ṣe iwadii orisu arun naa ṣabẹwo si China ti arun naa ti ṣan wa, wọn si fẹnuko pe ara ẹyẹ adan ni arun ọhun ti wa, amọ awọn si nilo lati ṣe awọn iwadii mi siwaju si.
Adari agba WHO, Tedros Adhanom Ghebreyesus sọ nigba naa pe ijọba China ko ni awọn akọsilẹ to to lati mọ orisun arun naa, ati pe wọn ko fun awọn ikọ oluwadii ọhun ni aye to tọ lati ṣe iṣẹ wọn.
WHO ni o ṣoro lati sọ pe inu laabu ni arun naa ti sọ mọ awọn eeyan lara.
Amọ lẹyin to sọ ọrọ naa lo fi kun pe o ṣeeṣe ko jẹ pe inu laabu ni arun naa ti bu jade, amọ awọn nilo ẹri to dantọ lati fidi ọrọ naa nidi.
Lẹyin naa ni iikọ miran ṣe ayẹwo lati mọ boya ara ẹranko ni arun ọhun ti wa tabi inu laabu lo ti bu jade.
Amọ nigba ti yoo fi di inu oṣu Kẹwaa ọdun kan naa, ijọba ilẹ Amẹrika sọ pe o ṣeeṣe ki wọn má le sọ orisun arun naa ni pato.
Atẹjade ijọba Amẹrika fi kun pe ki ṣe pe awọn eeyan kan mọọmọ ṣeda arun naa lati lo gẹgẹ bi ohun ija ogun.
Wọn fi kun pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ara ẹranko lo ti wa, tabi ko bu jade lati inu laabu.
Ṣugbọn China ti so pe kii ṣe inu laabu lo ti bu jade.
Iye iwọn arun naa to le ran eeyan
Awọn onimọ sọ pe o ṣoro lati mọ iye iwọn kokoro arun naa ti eeyan le mi simu tabi to le wọ ẹnu ki arun ọhun to le bẹrẹ si n gbogun ti ara ẹda.
Ajọ to n ri si ọrọ ajakalẹ aru nilẹ Amẹrica, CDC sọ pe awọn ko tii le sọ ni pato iye iwọn kokoro arun naa to le ṣakoba fun agọ ara eeyan.
Wọn ni "A ko le sọ boya awọn patiku bii mẹwaa ni o tabi ẹgbẹrun kan tabi ẹgbẹrun mẹwaa."
Wayi o, awọn onimọ ti n ṣe iwadii lọwọ lati mọọmọ fi arun naa si ara awọn eeyan to jọwọ ara wọn silẹ fun iwadii, ki wọn le ni oye iye iwọn patiku arun naa to le ran eeyan.
Iye iwọn agboguntaisan "Antibody" to le daabo bo agọ ara lọwọ arun Covid-19
Lọwọ yii awọn onimọ ko tii le sọ iye iwọn agboguntaisan, iyẹn "Antibody" ti yoo daabo bo agọ ara eeyan lọwọ arun Covid-19.
Amọ awọn onimọ naa fẹnuko pe ti wọn ba mọ iye iwọn agboguntaisan to le sabo lori eeyan lọwọ Covid-19, yoo ran awọn lọwọ lati gbogun ti arun naa.
Wọn si ti gba gbogbo eeyan niyanju lati maa tẹle awọn ilana to rọ mọ arun naa, bii fifọwọ ẹni loorekoore pẹlu omi ati ọṣẹ, yiyago fun ipejọ elero pupọ ati lilo ibomu lawujọ.