Ọlópàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí agbébọn tó jí èrò gbé, sẹkú pa dírẹ́bà ní pópónà márosè Èkó sí Ibadan

Ọkunrin agbebọn

Oríṣun àwòrán, other

Awọn afurasi agbebọn kan ti ji awọn arinrinajo marun un gbe lọ lagbegbe Onigari, loju ọna marosẹ Eko si Ibadan lẹyin ti wọn yinbọn pa awakọ wọn.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, orukọ awakọ ti wọn yinbọn pa ni Oluwatosin Aruwajoye, nigba ti ẹlomiran, Ibrahim Tiamiyu, fara pa lẹyin ti ọta ibọn ba ni itan.

Iroyin ni iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bii aago mẹfa idaji, amọ ọkan lara awọn ero ọkọ naa moribọ.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn agbebọn naa kọlu ọkọ Toyota Sienna to ni nọmba idanimọ "MUS 493 HH" to n ko ero lati ilu Ibadan lọ si ilu Eko.

Ni kete ti awọn arinrinajo naa de agbegbe Onigari ni awọn ọdaran ọhun jade lati inu igbo, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn soke ni lemọ-lemọ.

Bi wọn ṣe n yinbọn yii ni awakọ ọkọ naa gbiyanju lati tete wa ọkọ ọhun kọja, amọ wọn yinbọn lu, eyii to ṣeku pa, ti ibọn si tun ba okunrin mii ni itan.

Lẹyin ti ẹgbọn okunrin ti ibọn ba ni itan gbọ nipa iṣẹlẹ naa lo tẹkọ leti lọ si agọ ọlọpaa Toll Gate lati fi ọrọ ọhun to awọn agbofinro leti.

Iroyin ni lẹyin naa ni awọn agbofinro lati ẹka Anti-Kidnapping Squad ati Toll Gate lọ sibẹ lati doola ẹni ti ibọn ba, ti wọn si gbe lọ sile iwosan.

Wọn tun gbe oku awakọ to jade laye lọ si ile iwosan Adeoyo, to wa ni Ring Road nilu Ibadan.

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́

Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Adewale Osifeso, ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Osifeso fi kun pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.