ASUU Strike: Àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ bèèrè ohun méjì lọ́wọ́ ìjọba, kí wọn tó fopin sí ìyanṣẹ́lódì

Awọn olukọ fasiti OAU

Oríṣun àwòrán, Emmanuel oloye

Àkọlé àwòrán, ASUU ṣalaye pe o di igba ti ijọba apapọ ba mu adehun to baa ṣe ṣẹ ki awọn to pada si ẹnu iṣẹ

Ẹgbẹ olukọ ni fasiti lorilẹede Naijiria, ASUU ti sọ ohun meji ti wọn fẹ lọwọ ijọba, ki wọn to fopin si iyanṣẹlodi wọn.

Iyanṣẹlodi naa ti dena awọn akẹkọọ fasiti lati pada si ileewe lẹyin ti ijọba apapọ paṣẹ ki awọn ileewe ṣi pada.

Aarẹ ẹgbẹ ASUU, Ọjọgbọn Biodun Ogunyemi ṣọ eyi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ogunyemi ni kii ṣe ifẹ inu awọn tabi imọ tara ẹni nikan lo mu wọn gunle iyanṣẹlodi, amọ nitori eto ẹkọ to dẹnukọlẹ ni.

Ẹnu iloro fasiti Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ijọba ko gbọdọ ma a wo awọn yara ikẹkọọ bi o ṣe bajẹ lai tun ṣe, pẹlu awọn ile ibusun awọn akẹkọọ ti ko ṣe e fi oju ri nitori wọn ti bajẹ patapata.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU ni eleyii ko jẹ ki awọn akẹkọọ ni ifọkanbalẹ ni ileewe wọn.

Lọna keji ẹwẹ, ijọba gbọdọ san owo osu oṣiṣẹ ti wọn jẹ awọn olukọ fasiti naa, ki wọn to wọle pada.

Àkọlé fídíò, Àwọn kan ṣónú bí wọ́n bá di gómìnà, ẹ fún wa láyè láti wá parí iṣẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ - Akeredolu

''Ohun ti a n beere fun ni ki ijọba san owo oṣu awọn olukọ, ki wọn si ṣe atunṣe to yẹ ni awọn ileewe fasiti.''

''Gbogbo ohun ti ẹgbẹ ASUU n ṣe ni ki awọn olukọ ati akẹkọọ le ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ.''

''Awọn olukọ ko yan iṣẹ lodi nitori imọ tara ẹni nikan, awa naa ni awọn ọmọ si ileewe, a si fẹ ki aye wọn dara.''

Àkọlé fídíò, Wo Adigun ọmọ ọdún mẹ́rin tí òwe Yorùbá àti ìtúmọ̀ gbó lẹ́nu rẹ̀ ju tìrẹ̀ lọ

Lori ibeere pe, ṣe awọn akẹkọọ yoo wọle pada nsi ileewe ni ọdun yii, esi ti ASUU fun awọn oniroyin ni pe, ijọba lo le e sọ igba ti awọn akẹkọọ yoo wọle pada, ti wọn ba ti dahun ibeere awọn.

Ẹgbẹ ASUU wa rọ awọn akẹkọọ lati ṣe suuru pẹlu awọn olukọ wọn, nitori gbogbo igbiyanju awọn olukọ ni wi pe, ki wọn le e fi sabuke wọn yangan ni ọjọ iwaju.