Tomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè
Ìbẹ̀rù, owó, ìpè pàjáwìrì fún mítìnì lóru kìí jẹ ki òṣèlú rọrùn fún obìnrin - Favour
Honorebu Tomomewo Favour to jẹ ọdọbinrin to n sọju ẹkun Ilajẹ Constituency sọ pataki ipa ọkunrin gẹgẹ bi oluranlọwọ fun obinrin to n ṣe iṣelu.
O sọ nipa iriri rẹ ni kikun ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba paapaa Ìdí tí obìnrin kò ṣe pọ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà .
- Àwọn òṣèré Yollywood tó ń pàrònú rẹ́
- EFCC: Ẹ yàgò fún MMM, àwa ké fún un yín tó o!
- Ètò sogúndogójì 'MMM' tún ti padà dé, rọ́bọ́ọ̀tì ni yóò maa ṣàkóso
- Àwọn àṣà àti ìse tó yọ obìnrin sílẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá
- Ọọ̀nì àléégbà dé bá ọ lálejò, kí ló máa ṣe?
- Lẹ́yìn ọlọ́pàá, VIO nìkan ló láṣẹ láti dá ọkọ dúró láìṣẹ̀ - Ọ̀gá VIO Eko
Honorebu Favour ni iṣẹ ọwọ oun ni baba isalẹ oun ṣugbọn o sọ ipa pataki ti Arabinrin Betty Anyanwu Akeredolu ko ninu irinajo oṣelu oun.
Bẹẹ, ti a kò ba ri ẹni ba la ni ọrọ iṣelu ni Naijiria, ọ̀là kìí yá.
Bakan naa ni Favour sọrọ lori awọn ipenija ti oun koju lagbo iṣelu nitori aiko owo silẹ.
O ni ọpọlọpọ agba ẹgbẹ ni ko ṣe ti oun nitori oun kọ̀ lati maa pin owó.
Tomomewo gba awọn obinrin to ba fẹ wọnu iṣelu Naijiria lọ ni imọran.
O sọ bi wọn ṣe le koju ẹ̀rù obìnrin ninu iṣelu.