Contortionist: Mo lè gbé ìfun mi pamọ́ ki n tún sé èémí pẹ́!

Àkọlé fídíò, Contortionist: Mo lè gbé ìfun mi pamọ́ ki n tún se èémí!

Ara mi rọ̀, kò si bí mi ò ṣe lè ká ẹsẹ̀ mi- Oyindamola.

Kò sí iṣẹ́ ti èèyàn kò lè yàn láàyò ni kete ti o ba ti ṣawari ẹbun ti Ọba òkè fi jinki rẹ.

Oyindamọla Kọlawọle Emmanuel ti o n lọ́ ẹran ara rẹ ati egungun rẹ fi da àrà to wù ú, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni 'Contortionist' ṣalaye ohun to ṣokunfa eyi fun BBC Yorùbá.

O ni aimọwe ohun daadaa nile ìwé lo jẹ ki oun ronu ọna miran ti oun fi le wulo lawujọ Yoruba gẹgẹ bii ọmọ Oodua gidi to fẹ gbe aṣa ga

Oyindamola sọrọ lori awọn ami ẹyẹ ti oun ti gba ati awọn aṣeyọri to ti ni lẹnu yiyan iṣẹ yii laayo.

O mẹnuba bi oun ṣe bẹrẹ pẹlu ijo ibilẹ nile iwe nibi ti oun ti rii pe ara oun ṣeé rọ́ si ipokipo tó bá wu oun.

Oyindamọla ni oun ṣetan lati maa kọ awọn ewe iwoyi ni iṣẹ yii ko lè tubọ jẹ itẹwọgba sii lawujọ Yoruba.

O gba awọn ọdọ nimọran pé ki wọn ṣawari ẹbun ti Ọlọrun fun wọn nitori kii ṣe gbogbo eeyan lo maa fi iwe kika jẹun bi igboro ṣe ri lasiko yii.

* A ko fẹ́ ki ẹnikẹni dan awọn iṣẹlẹ inu fidio yii wo nitori pe o léwu.

Eni to n ṣee yii jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa ara lílọ́pọ̀ ni.