Ọdun mẹta lẹyin iku Arisekọla: Kin lo ranti nipa rẹ

Oríṣun àwòrán, Tribune
'Ida mẹta ni Ibadan pin si. Arisekola Alao ko ida kan, Adedibu ko ikeji ,Olubadan lo ko mejeji to ku pọ.'
O se se ki ẹ ti gbo ki tọmọde tagba ma je ọrọ yi lẹnu.
Awọn onwoye ni apejuwe yi se rẹgi paapa julọ ta ba n sọrọ nipa Aarẹ Musulumi tẹlẹ fun gbogbo ilẹ Yoruba.
Ninu osu keji ọdun 2018 niArisekọla ko ba pe ẹni ọdun mẹtalelaadọrin.
A ba awọn to mo bujebudanu oloore yi sọrọ nipa igbe aye rẹ ati ipa to ko ninu ọrọ ilẹ Yoruba, ẹsin Islam ati idagbasoke orileede Naijiria.
Arisekola wulo pupo fun ilu
Se asọ to ba kangun si eegun ni wọn npe ni Jẹpẹ, Asofin Adeniyi Akintola, tii se agba amofin (SAN) je ọkan lara awọn to sunmọ Arisekola Alao nigba to wa laye.
Agbẹjọro naa ni Arisekọla Alao kii se Ọlọrun sugbọn akanda eniyan ni.'
'Oniwarẹlẹ ni Arisekola Alao. Ọpọ igba si ni o ma n tọrọ aforijin lọdọ ẹni to to ati ẹni ti ko to-o. Lọrọ oselu ati ẹsin ,o ko ipa manigbagbe.'

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

O dẹrin pẹẹkẹ awọn to ba wa ninu ibanujẹ
Adeolu Adeleke (Abẹnugan ile asofin ipinle Ọyọ laarin ọdun 2003-2007) se iranti Arisekola Alao pẹlu ibanujẹ ọkan.
O ni Arisekola Alao se ''gudugudu meje, yaaya mẹfa, gẹgẹ bi ọmọbibi ilẹ Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ati orileeede Naijiria lapapo''
Arisekola jẹ ilumoka oloseelu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Atiku Abubakar
Arisekola Alao je Ọlorun ni pe lọjọ kẹtadinlogun osu kefa ọdun, 2014.













