Ekiti Election: Bọ́mọ kò bá bá ìtàn ó di dandan kó bá àrọ́bá

Àwọn ènìyàn Ekiti yóò pààrọ̀ Fayooṣe sí gómìnà míì lónìí
Ọjọ́ kìnní, oṣù kẹwaa, ọdún 1996 nijọba Nàìjíríà dá ipinlẹ Ekiti pẹlu ipinlẹ marun un miran silẹ lábẹ ijọba ologun Sani Abacha. Ipinlẹ Ondo lo bí ipinlẹ Ekiti. O ni ijọba ibilẹ mẹrindinlogun nínú eyi ti eto idibo yoo ti waye kaakiri lonii.
Ọ̀pọ́ àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló ń bèrè ìdí abájọ ti ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Ekiti fí yàtọ̀ sí àwọn ìdìbò tó kú.
Ní ti Ekiti, ìjà tó tẹ̀lẹ̀ ètò ìdìbò April 14 ọdún 2007 lo fi di ọrọ ile ẹjọ́ tó ń ri si awuyewuye tó súyọ lẹ́yìn ìdìbò, (Tribunal).
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (INEC) ka èsì ìbò pé Oní ìmọ̀ ẹrọ Segun Oni ló jáwe olúbori, tí Ọ̀mọ̀wé Kayode Fayemi sì fáriga pé òun ló jáwé olúbori, èyí ló fàá ti ọ̀rọ̀ fí di ti ilé ẹjọ́ sùgbọ́n tó fìdí rẹmi bọ̀ níbẹ̀.
Ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọn tun ibo naa di kile ẹjọ to gbe e fun Fayẹmi.

Ètò ìdìbò yìí f'ọdun 2018
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oludije lo ti jade lati dije fun ipò gomina ipinlẹ Ekiti lọdun yii. Diẹ lara wọn ni:
Ṣáájú ìdìbò 2018
Oriṣiiriṣi nkan lọ ṣẹlẹ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu to n dije fun ipo gomina Ekiti paapaa àwọn ti PDP ati APC.

Bii ti o dabi ibẹrẹ iṣẹle Fayoṣe ati Fayẹmi, ọpọlọpọ awuyewuye lo ti waye laarin awọn ẹgbẹ oselu mejeeji eyi ti Aarẹ Buhari fi wa si Ekiti fun ipolongo alaafia pe ‘Àláfíà ọmọ Naijiria lo jẹ mí logun'.
Ọpọlọpọ nkan lo ṣẹlẹ ni eyi ti Fayoṣe figbe ta pé wọ́n fẹ́ gbẹ̀mí òun lẹyin to dara nibi ipolongo ko to di ero ile iwosan.
Eyi lo tun mu ni eyi to tun bi ero pe Fayoṣe yin Ngige fún bó se polongo ìbò fún PDP
Bayii opolopo igbese nijoba atawon agbofinro ti gbe ki eto idibo Ekiti le jẹ aṣeyọri Wo ibi tí ìgbáradì fún ìbò gómìnà l'Ékìtì dé dúró
Ajọ eleto idibo INEC naa sọrọ lori iṣẹ ti wọn ti ṣe de idibo Ekiti pe:
Bi àwọn kan ṣe n yin Fayose ni awọn mii gba pe ọgbọn lo n da pe Fayose kọ́ ni olóṣèlú tí yóò kọ́kọ́ kán l'ọ́rùn'
Bayii àwọn eniyan Ekiti n fẹ alaafia, wọn de n fẹ jade dibo fun ẹni to wu wọn loni




















