Ekiti Decides: Buhari ni òun kọ́ ló rán àwọn darandaran nisẹ

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni, kii ṣe wi pe oun ko gbe igbese to lami-laaka lori isekupani awọn Fulani Darandaran nitori pe oun jẹ Fulani ni orilẹede Naijiria.
Buhari sọ eyi nibi asekagba ipolongo ibo to waye ni ọjọ isẹgun ni ilu Ado Ekiti fun Dokita Kayode Fayemi, to n dije dupo gomina ninu idibo ti yoo waye ni Ọjọ Satide, ọsẹ yii.

Awọn leekan-leekan to wa nibi ipolongo ibo naa ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun, Gomina Ipinlẹ Ọyọ, Abiola Ajimobi, Gomina ipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola, Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ati Yahaya Bello ti ipinlẹ Kogi.
Papa isere Oluyemi Kayode ni olu olu- ilu ipinle Ekiti, Ado-Ekiti ni ipolongo ibo naa ti waye.









