Ekiti Election: Ẹ́gbẹ̀rún mẹ́rin nàirà ni ẹnikọ̀ọ̀kan ń gbà
Fidio to wa loke yii lo n salaye bi awọn eeyan iluEkiti se n gba ẹgbẹrun mẹrin naira saaju ididbo gomina.
Ni bayii to ku wakati mẹrinlelogun pere ki eto idibo gomina ni ipinlẹ Ekiti bẹrẹ, BBC ri arigbamu pe awọn oloselu kan ti n pin owo fawọn oludibo ni ipinlẹ Ekiti.
Iyalẹnusi lo jẹ ni ọsan oni nigba ti ikọ iroyin BBC se awari awọn eeyan kan ti wọn n rọ kẹti-kẹti lọ si ile ijọba atijọ to wa ladugbo Okesha ni ilu Ado Ekiti, tii se olu ilu ipinlẹ Ekiti.

Ninu iwadi ikọ iroyin BBC, a se awari rẹ pe kaadi idibo ni awọn eeyan naa mu dani, ti wọn fi n lọ gba ẹgbẹrun mẹrin naira ẹni kọọkan.
Bi o tilẹ́ jẹ́ pe a tiraka lati mọ ẹgbẹ oselu to n pin owo naa fawọn oludibo, sugbọn idahun ikọọkan wọn yatọ sira.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bi ẹnikan se ni Fayẹmi ni, ni ẹlomin ni PDP ni, eyi ti ko jẹ ka ri arigbamu gidi.
Ori ẹrọ ibaraẹni sọrọ alagbeka ni wọn ti n pe ara wọn lati wa gba owo, ni ibamu pẹlu wọọdu ti ẹni kọọkan wọn ti wa.










