Winter Olympics: Saraki kan saara si awọn ọmọ Naijiria mẹta to ndije

Awọn ọmọbinrin mẹta ti yoo soju ilẹ Naijiria nibi idije Olimpiiki ori yinyin, (Winter Olympics) fun igba akọkọ.

Aarẹ ile asofin agba lorilẹede Naijiria, Bukọla Saraki, ti ransẹ "ẹ ku isẹ takuntakun" si awọn ọmọ orilẹede yii mẹta kan ti wọn ngbaradi lati kopa nibi idije olimpiiki ti yoo waye lọdun yin.

Awọn ọmọ orilẹede Naijiria naa, Seun Adigun, Ngozi Onwumere ati Akuoma Omeoga ngbaradi gẹgẹbi ikọ akọkọ lati ilẹ Afirika ti yoo kopa ninu idije olimpiiki ori yinyin (Winter Olympics) nigba ti wọn yoo maa kopa ninu idije kẹkẹ ori yinyin ti wọn npe ni "Bobsledding"

Ninu ọrọ iyanju to fi ransẹ si awọn oludije mẹta naa lori ikanni ayelujara twita rẹ , Sẹnatọ Bukọla Saraki kan sara si awọn ọmọbinrin mẹta naa fun akitiyan wọn lati rii wipe wọn kogoja ninu idije naa.

"Ori mi wu pẹlu isẹ takuntakun Seun Adigun, Ngozi Onwumere ati Akuoma Omeoga.

Awọn ọmọbinrin mẹta yii la gbogbo wahala ati isoro to wa ni ọna wọn kọja lati kopa ninu idije kẹkẹ ori yinyin ti wọn npe ni "Bobsledding" eleyi ti yoo maa jẹ akọkọ iru rẹ ni orilẹde yoowu nilẹ Afirika yoo maa kopa nibi idije Olimpiiki oniyinyin. (Winter Olympics)"