You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Damola Olatunji fojú balé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó dúnkookò mọ́ ọlọ́pàá àtàwọn ẹ̀sùn míì
Damola Olatunji ti foju bale ẹjọ lẹyin ede aiyede to waye laarin oun atawọn ọlọpaa kan lagbegbe Abule Ẹgba, niluu Eko.
Ṣaaju ni awọn ọlọpaa ọhun ti kọkọ ti Damola mọle nitori iṣẹlẹ naa.
Ni bayii, wọn ti tu oṣere naa silẹ ni agọ ọlọpaa lẹyin ti wọn foju bale ẹjọ laarọ ọjọ Iṣẹgun.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti ni ko maa lọ sile rẹ, ọrọ naa ko tii yanju rara.
Gẹgẹ bii ohun ti agbẹjọro rẹ, Sulayman Alabi sọ, nnkan bii ẹsun mẹrin ọtọtọ ni awọn ọlọpaa fi kan oṣere tiata naa nile ẹjọ.
O ni "Awọn ọlọpaa kan awọn ẹsun kan ti ko lẹsẹ nilẹ si lọrun."
"Lara ẹsun naa ni pe o kọlu ọlọpaa lọna aitọ, wọn ni o di wọn lọwọ lati ṣe iṣẹ wọn, wọn ni o parọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa lori ayelujara lọna ati ba orukọ wọn jẹ, ati bẹẹ lọ."
Alabi sọ pe awọn yoo joko lati jiroro lori igbesẹ ti awọn yoo gbe lori ọrọ naa ti akoko ba to.
O pari ọrọ rẹ pe ile ẹjọ ti sun igbẹjọ naa si ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2022.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Damola Olatunji di èrò àtìmọ́lé nítorí èdè àìyedè tó wáyé láàrin òun àti ọlọ́pàá l'Eko
Gbajugbaja oṣerekunrin, Damola Olatunji ti di ero atimọle ọlọpaa nipinlẹ Eko, lẹyin ti iroyin sọ pe ede aiyede da oun ati awọn ọlọpaa kan pọ ni agbegbe Abule-Egba.
Ninu fidio kan to gba ori ayelujara ni ọjọ Aje, a rii pe idarudapọ n waye, ti Damola si n pariwo ninu fidio naa pe awọn ọlọpaa naa fi ọwọ agbara fiya jẹ ọkunrin ọlọkada kan.
O ni wọn gba ọkada lọwọ ọkunrin naa, ti oun si sọ fun wọn pe ki wọn o jẹ ki ọkunrin naa wa ọkada rẹ lọ si agọ wọn fun'ra rẹ, nitori pe iṣekuṣe ni ọlọpaa n ṣe ọkada ọkunrin naa.
Olatunji sọ pe nkan ti oun sọ ko ju bẹẹ lọ, ti ọlọpaa kan fi kọju ija si oun pe "ẹranko" ni oun.
Damola ṣalaye pe bi oun ṣe tako pipe oun ni ẹranko bi ọlọpaa naa ninu, ti ọrọ naa si di awuyewuye.
O ni inu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ni oun wa lasiko naa, ti oun fi dasi bi wọn ṣe fẹẹ fi iya jẹ ọkunrin ọlọkada naa.
O ni niṣe ni wọn yin afẹfẹ taju-taju mọ ọkunrin naa ati awọn aladugbo to ṣugba wọn.
Bakan naa lo fi ẹsun kan wọn pe ẹnikan lara awọn ọlọpaa naa ja foonu gba lọwọ oun ati amugbalẹgbẹ oun, nitori pe oun n ya fidio wọn.
Wakati diẹ lẹyin ti iṣẹlẹ naa wyae ni Olatunji fi sori ayelujara ibaraẹnisọrọ Whatsapp rẹ pe awọn ọlọpaa ti fi oun si atimọle.
Ninu ọrọ ti agbẹjọro rẹ sọ fun BBC Yoruba ni owurọ ọjọ Iṣẹgun, Agbẹjọro Adewale Alabi sọ pe onibaara oun ati amugbalẹgbẹ rẹ ṣi wa ni ahamọ ọlọpaa.
Ọgbẹni Alabi sọ pe awọn n duro de Ọga Agba ọlọpaa ni agbegbe ọhun ki wọn o le jiroro lori gbigba beeli wọn.