Premier League: Crystal Palace yẹ̀yẹ́ Arsenal bí Everton ṣe dígbájú ru Manchester U

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Tẹni to de laari, a ko mọ tẹni to n bọ lọrọ awọn ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League to waye lọjọ Aiku.
Lẹyin ti Everton pokọ iya fun Manchester United ni papa isẹre Goodison Park tan ni Crystal Palace ki Arsenal mọ lẹ nile wọn ti wọn si ki bẹndẹ siwọn ninu.
Ami ayo mẹta si meji ni Palace fi ṣagba fun awọn Gunners nile wọ.
- Ayé le, ìbòsí ò! Everton já Manchester United sí ìhòhò lọ́jọ́ Àjíǹde
- Beckham, àgbábọ́ọ́lù tẹ́lẹ̀ rèé tó ń sọ èdè Yorùbá
- UEFA Champions League: Barca yọ Man U dànù bí ẹni yọ jìgá!
- Ààrẹ Buhari kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí àwọn èèyàn 207 tí wọ́n pa lọ́jọ́ Àjíǹde
- Omotola Jalade ní Nàìjíríà dàbí ọ̀run àpáàdì lábẹ́ ìjọba Buhari
Arsenal si wa ni ipo kẹrin lori tabili Premier League, ṣugbọn Chelsea yoo gba ipo naa mọ wọn lọwọ ti wọn ba jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn lọjọ Aje.
Esi ere bọọlu yii jẹ iyalẹnu fun awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lẹyin ti wọn na Napoli tan ninu idijẹ Europa League.









