Champions League: Tottenham fìyà jẹ Man City

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ifẹsẹwọnsẹ UEFA Champions League laarin Tottenham ati Manchester City gbona girigiri koda ami ayo kan sodo ni Tottenham fi gbẹyẹ lọwọ manchester City.

Ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ree ni ipele ''quarter finals'', ọsẹ to n bọ ni wọn yoo gba ẹlẹẹkeji.

Ikọ Manchester City fẹ gba ami ẹyẹ mẹrin ọtọtọ ni saa yii eyi ti idije UEFA Champions League jẹ ọkan lara wọn.

Agbabọọlu ti orukọ rẹ n jẹ Son lo gba goolu kan ṣoṣo ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun wọ le.

Ẹgbẹ agbabọọlu Man City ti gba ọkan ninu ami ẹyẹ mẹrin ọhun, lẹyin ti wọn gba ife ẹyẹ Carabao Cup lai pẹ yii.

Aṣọle fun Tottenham Hugo lloris mu pẹnariti ti ẹlẹsẹ ayo Man City Sergio Aguero gba.

Ko si ẹgbẹ agbabọọlu kan to ti gba ami ẹyẹ mẹrin ri ni saa kan ninu itan ere bọọlu nilẹ Gẹẹsi.

Igba keji ree ti Tottenham yoo lo papa iṣerẹ tuntun wọn fun ere bọọlu lẹyin ti wọn papa isẹre naa pẹlu ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League eleyi ti wọn fi na Cystal Palace.

Ifẹsẹwọnsẹ mii to wa ninu idije UEFA Champions League lalẹ ọjọ Iṣẹgun yoo waye ni papa iṣere Anfield nibi ti Liverpool yoo ti gbalejo FC Porto.

Naby Keita ati Roberto Firmino gba goolu meji sawọn FC Porto bi Liverpool ṣe bori.

Liverpool de ipele aṣekagba Champions League ni saa to lọ ṣugbọn ikọ Real Madrid lo gba ife ẹyẹ naa.