WrestleMania 35: Kingston fẹnu ọmọ Amẹrika gbo lẹ̀ láti gbàmì ẹ̀yẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aileja lojude baba mi ko de bi ni Yoruba maa n wi.

Bẹẹ gẹgẹ lọrọ Kofi Kingston ri o. Kingston to jẹ ọmọbibi orilẹ-ede Ghana lo foju ọmọ Amẹrika, Daniel Bryan gbo lẹ to fi gba ami ẹyẹ ijakadi WrestleMania.

Kingston ti di ọmọ ilẹ Afirika keji bayii ti yoo gba ami ẹyẹ WrestleMania, bẹẹ oun ni ẹni kẹrin ti yoo di ajijakandi lagbaaye.

Mark Henry, Booker T ati The Rock ni wọn ti gba iru ami ẹyẹ bẹẹ tẹlẹ.

Ni iwaju ẹgbẹrun lọna ọgọrin awọn oluworan ni Kingston ti run Bryan mọlẹ to si fẹnu rẹ gbo lẹ, lẹyin naa ni oludari ija ọhun ka meni, meji, mẹta ti o si gbọwọ rẹ soke.

Awọn oluworan ba yanu lẹẹ bi aja mi lo paa nitori ko si ẹni to ro pe nnkan yoo yi biri fun Bryan to jẹ alako Kingston.

Ohun to n fa awuyewuye lori ayelujara bayii ni pe bo ya Kingston ni ajijakadi akọkọ ti yoo kọkọ gba ami ẹyẹ agbaye.

Ọpọ awọn ololufẹ ere idaraya ijakadi ni wọn sọ pe The Rock ti ọpọ ka kun alawọdudu akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ WWE kii ṣe alawọdudu.

Ṣugbọn The Rock fun ra rẹ ti sọ pe apa kan eeyan dudu loun ti apa keji si jẹ ọmọ ilẹ Samoa ni erekuṣu nitrori awọn alaṣẹ WWE ko ka kun alawọdudu.

Koko to wa ninu rẹ ni pe orukọ Kofi Kingston ti wọ iwe itan gẹgẹ bi alawọdudu to gba ami ẹyẹ WWE.