You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdájọ Ademola Adeleke l'Akure kò túmọ sí pé o kún ojú òṣùwọ̀n-Timothy Owoeye
Olori ọmọ ẹgbẹ to pojulọ nile asofin ipinlẹ Osun,Timothy Owoeye ti dasi ọrọ idajo ti ile ẹjọ kotẹmilọrun kan nilu Akure fi sita lori kikaju osuwọn Sẹnẹtọ Ademola Adeleke lati du ipo Gomina .
Lọjọ abamẹta ni igbimọ ipolongo Sẹnẹtọ Adeleke fi atẹjade sita nipa idajọ yi eleyi ti wọn ni o fihan pe lootọ ni pe Sẹnetọ Adeleke kaju iwọn lati du ipo Gomina.
Koda gbajugbaja olorin takasufe Davido ti Adeleke jẹ ibatan rẹ fi ikini soju opo Twitter rẹ lati ba Adeleke yọ lori ohun ti ile ẹjọ wi yi.
Amọ asofin Owoeye ni ki Davido ma ti yọ ju nitori pe idaj naa ko tunmọ si pe Adeleke ti gba idajo lori ọrọ yi.
Owoeye ni Adeleke ṣi yi ni ẹjọ niwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun Abuja fun idi eyi,ki awọn eeyan ma ṣe gba ọrọ ẹgbẹ PDP gbọ lori pe Adeleke le du ipo Gomina.
O ni ọmọ ẹgbẹ PDP Akin Ogunbiyi lo gbe ẹjọ na lọ si iwaju ile ẹjọ lakure atti pe ko ni ohun kankan ṣe pẹlu idajọ ti ile ẹjọ kotmilọrun ti wọn ko ti da nilu Abuja.
Irú ìdájọ wò ní Ademola Adeleke gbà nílé ẹjọ ko-te-mi-lorun?
Gẹgẹ bi ohun ti a ri gbọ lẹnu Dele Adeleke ati atẹjade kan ti igbimọ ipolongo Sẹnẹtọ Adeleke fi sita lorukọ agbẹjọro Niyi Owolade idajọ ti ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Akure da ti fi han gbangba pe idajo ile ẹjọ giga nilu Bwari ko fẹsẹrinlẹ.
Wọn ni ohun to de ba idajọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ PDP kan gbe lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun Lakure naa lo de ba ti Bwari latari pe awọn to gbejọ naa wa ko gbe ẹjọ naa wa lasiko ti ofin fi aye kalẹ fun igbẹjọ ọrọ idibo.
Ni iwoye wọn, wọn sọ pe awọn ṣe alaye yi niwaju adajọ to gbẹjọ Adeleke ni ilu Bwari L'abuja ṣugbọn wọn ko gba ọrọ naa wole.
Ni bayi ti ile ẹjọ Akure ti ni Adeleke koju ọsuwọn,igbimọ ipolongo rẹ ni ko si nnkan mi ju ki ile ẹjọ ti yoo gbọ ẹjọ kotẹmilọrun awọn L'Abuja naa dajọ to jọ iru ti Akure.
Lọjọbọ ti ṣe ọjọ kẹrin oṣu Kẹrin ni Adeleke kọwe ẹjọ kotẹmilọrun ninu iwe ipẹjọ FCT/HC/BW/80/122/2018 lọ si ile ẹjọ giga Abuja.
Ninu iwe yi, o ni ohun fẹ ki ile ẹjọ kotẹmilọrun fọwọ rọ idajọ ile ẹjọ giga to ni ohun ko yẹ ni ẹni to n du ipo Gomina.
Bi a ko ba gbagbe lọjọ kejioṣu Kẹrin ni ile ẹjọ giga ni Bwari nilu Abuja dajọ pe Ademola Adeleke ko kaju osuwọn lati du ipo Gomina ninu idibo Gomina to waye ldun to kọja nipinl Osun.