You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Osun elections: Ademọla Adeleke, Fayoṣe, Atiku sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́
Ẹni ti ile ẹjọ ṣẹṣẹ kede pe ilu dibo yan gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti ṣalaye pe Ọlọrun ni oun fi ọpẹ fun lori idajọ to waye naa.
Sẹnetọ Adeleke to sọrọ ni oju opo twitter rẹ ni 'Ogo ni fun Oluwa"
Yatọ si Adeleke, Ọpọlọpọ awọn ọtọkulu lo ti sọrọ lori ọrọ yii.
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayose ṣalaye pe lẹyin Ọṣun, Ekiti lo kan lati bọ si ọwọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Oludije fun ipo arẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ti ki Adeleke ku oriire idajọ to ṣẹṣẹ gba ni ile ẹjọ.
Atiku ni o fihan pe 'lootọ, ẹka idajọ ni ireti araalu ati olugbeja iṣejọba tiwantiwa."
Bakan naa, gbajugbaja olorin takasufe to tun jẹ mọlẹbi Adeleke ni imọlẹ lo de si ipinlẹ Ọṣun bayii.
O wa ki aburo baba rẹ ku oriire.