La liga: Barcelona lè téńté orí tábìlì pẹlú àmì ayo mọ̀kànlá

Messi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Messi dti jẹ goolu 33 ni saa bọọlu ọdun yi nikan

Ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ti le iwaju awọn akẹgbẹ rẹ lori afara La liga pẹlu ami ayo mọkanla ti wọn fi n ja awọn iyoku silẹ.

Luis Suarez ati Lionel Messi ni wọn jẹ goolu meji ti aṣeyọri yi fi waye ti o si jẹ ki o dabi pe Barcelona yoo gba ife ẹyẹ karun un lera laarin saa meje.

Atamatase tẹlẹri fun ẹgbẹ Chelsea Diego Costa ni adari idije juwe ile fun nigba to gba kaadi alawọ pupa ni iṣẹju kẹtadinlọgbọn ifẹsẹwọnṣẹ naa.

Aṣọle Athletico Madrid, Jan Oblak gbiyanju pupọ lati koju awọn atamatase Barcelona ṣugbọn ẹpa ko boro nigba ti Luis Suarez jẹ goolu akọkọ ni iṣeju marun un si ipari ifẹsẹwọnṣẹ ọhun.

Ko ju iṣẹju kan lẹyin igba ti Suarez gba bọọlu wole lati ọna jinjin ti Lionel Messi na gbe iṣe rẹ de.

Messi ge awọn agbabọọlu Athletico meji ati aṣọle wọn Oblak ki o to gba bọọlu wọ awọn lati jẹ goolu ikẹtalelọgbọn rẹ ni saa bọọlu ọdun yi.

Ẹgbẹ Barcelona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idije ju idije lọ

Atrhletico ṣapa lati da goolu kan pada ṣugbọn pabo ni igbiyanju wn jasi.

Àkọlé fídíò, Ayekofẹnifọrọ: Ó yá, ẹ fi àmì sórí ọ̀rọ̀ náà.

Ohun to ku bayi fun wọn ni ki wọn ma sare du ipo keji pẹlu Real Madrid ninu ifẹsẹwọnsẹ to ku.

Lionel Messi ti pegede bayi ju ẹnikini lọ ni La liga pẹlu iye ifẹsẹwọnsẹ ti o ti ti fakọyọ.

Iker Casillas lo gba ami yi tẹlẹ ṣugbọn Messi ti lewaju rẹ pẹlu ifẹsẹwọnsẹ 335 to ti pegede ninu rẹ.

Àkọlé fídíò, Jawahir Roble:Hijab tí mò n lò kó jẹ́ kọ́kọ́ jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn agbábọ́ọ̀lù mi