You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Arsenal: Emery ní òun fẹ́ kí agbábọ́ọ̀lù tí kò fakọyọ bínú
Akọnimọọgba ikọ Arsenal Unai Emery sọ oju abẹ niko nigba to sọ pe ko kan oun ti awọn agbabọọlu ikọ naa ba binu ti oun ba parọ wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan.
Ọrọ yii jẹ yọ lẹyin ti ẹlẹsẹ ayo Pierre-Emerick Aubameyang koro oju nigba ti wọn parọ rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ Arsenal pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Newcsatle lẹyin ti Aubameyang kuna lati fakọyọ ninu ere bọọlu naa.
Akọnimọọgba Emery fi kun ọrọ rẹ pe oun fẹ ki gbogbo agbabọọlu ikọ naa maa gbiyanju agbara wọn lati fakọyọ nigbakugba ti wọn ba lanfani lati ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Henrikh Mkhitaryan lo rọpo Aubameyang ni iṣẹju mọkandinlaadọrin ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun to waye ni papa iṣere St. James Park ninu idije Premier League.
Granit Xhaka ati Mesut Ozil lo kọkọ gbayo kọkọkan wọle nigbati Arsenal bẹrẹ si siwaju Newcastle pẹlu ami ayo meji sodo.
Ciaran Clark to jẹ agbabọọlu Newcastle da ayo kan nigbati ifẹsẹwọnsẹ ku die ko pari, ṣugbọn Arsenal pada jawe olubori.
Ipo keje ni ikọ Arsenal wa bayii ninu idije Premier League lẹyin ti wọn lu Newcastle mọle.