You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
George Weah: Nàìjírìa fìyà jẹ Ààrẹ Liberia pẹ́lú ikọ̀ rẹ̀
Aarẹ orilẹede Liberia George Weah pada sori papa ni ọmọ ọdun mọkanlelaadọta nibi to ti kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ pẹlu orilẹede Naijiria lọjọ Iṣẹgun nilu Monrovia.
Ṣugbọn Aarẹ Weah to gboye agbabọọlu to pegede julọ lagbaye lọdun 1995 ko le gba ikọ agbabọọlu orilẹede rẹ silẹ lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria fiya jẹ wọn pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan.
Agbabọọlu tẹlẹ ri Weah to jẹ alawọdudu akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ lagbaye wa lori papa fun iṣẹju mọkandinlọgọrin ki wọn to paarọ rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Orilẹede Liberia ṣe agbekalẹ ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ọhun lati fi adagba jẹẹsi pẹlu nọmba mẹrinla(14) ti Weah wọ nigba ti o n gba bọọlu rọ.
Henry Onyekuru ati Simeon Nwankwo lo gba ayo meji sawọn fun Nigeria ki agbabọọlu Kpah Sherman to d'ayo kan pada pẹlu pẹnariti.
Weah gba bọọlu fun awọn ikọ bi Monaco, Paris Saint-Germain ati Marseille nilẹ Faranse ati AC Milan orilẹede Italy ki o to fẹyinti.