You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Community shield: Manchester city na Chelsea pẹ̀lú 2-0
Goolu meji ọtọọtọ lati ẹsẹ atamatase agbabọọlu Manchester city, Kun Aguero lo fun Manchester city ni ife ẹyẹ Community shield ti ọdun 2018.
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city pẹlu Chelsea forigbari ninu idije Community Shield lọjọ aiku ni papa iṣire Wembley ni ilu London.
Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo fi pari, goolu ti Aguero gba wọle ni iṣẹju kẹtala ati ikejidinlọgọta ifẹsẹwọnsẹ naa lo la aarin Manchester City ati Chelsea.
Manchester city ni ẹgbẹ agbabọọlu to gba liigi saa to kọja nigbati Chelsea gba ife ẹyẹ FA ni orilẹede Gẹẹsi.
Idije ife ẹyẹ Community shield yii ni ifẹsẹwọnsẹ to maa n ṣe atọna fun saa liigi tuntun lorilẹede Gẹẹsi.
Idije yii ni o jẹ idanwo akọkọ fun olukọni tuntun fun ikọ Chelsea Maurizio Sarr lẹyin ti awọn alaṣẹ ikọ Chelsea le olukọni wọn tẹlẹ, Antonio Conte ni ọjọ kẹtala oṣu keje ọdun yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Eyi ni igba akọkọ ti Manchester city yoo maa gba ife ẹyẹ naa lati ọdun 2012 nigba ti wọn na ẹgbẹ agbabọọẹu Chelsea kan naa pẹlu ami ayo mẹta si meji.
Ni bayii, ẹgbẹ agbabọọlu city yoo maa koju Arsenal ni papa iṣire Emirate ni ọjọ aiku to nbọ fun ibẹẹrẹ saa liigi tuntun ti Che;sea yoo ba Huddersfield figagbaga.