You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
World Cup 2018: England pegedé fún ìpele kejì ní Russia
Ikọ England fiya jẹ Panama pẹlu ami ayo mẹfa ṣi ẹyọkan ninu idije ife ẹyẹ agbaye World Cup 2018 to n lọ lọwọ l'orilẹede Russia.
Ayo mẹta ọtọtọ ni ẹlẹsẹ ayo Harry Kane gba sawọn bi ikọ England ti pegede bayi lati kopa ninu ipelekeji idije ife ẹyẹ agbaye t'ọdun yii.
Adiẹyinmu fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City John Stones naa fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ọ'un lẹyin igbati o gbayo meji sawọn.
Jesse Lingard to n gba bọọlu fun Manchester United naa ko gbẹyin bi o ti gba ami ayo kan sawọn.
Felipe Baloy dayo kan pada ninu mẹfa fun ikọ Panama, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.
Eyi ni igba akọkọ ti ikọ England yoo gbayo mẹrin okere tan wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ kan ninu idije ife ẹyẹ agbaye lati ọdun 1966.