You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Serena ṣèṣe pẹ̀lú apá, ó ni òun ń lọ tọ́jú ara òun
Apá yíyọ lásìkò ìdíje kò yọ Serena Williams sílẹ̀
Àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù tẹnísìì, Serena Williams, ti yọwọ kuru ninu idije French open to n lọ lọwọ lẹyin ti o farapa pẹlu apa rẹ.
Serena to yẹ ko koju alatako rẹ Maria Sharapova lọsan ọjọ Aje tẹlẹ ko ni l'anfani lati dije mọ lataari ifarapa naa.
Serena to jẹ ọmọ orilẹ-ede Amerika ko tíì nijakulẹ lọwọ Sharapova lati ọdun 2004.
Akọsilẹ fi han pe Serena ti yọwọ ninu idije tẹnísìì nigba mẹẹdogun, ṣugbọn ko ti yọwọ ninu idije Grand Slam ri.
Ẹwẹ, alatako rẹ Maria Sharapova ti pegede bayi fun isọri komẹsẹ-ọ-yọ ẹlẹni mẹjọ latari ifarapa Serena.