You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Athletico Madrid já ìrètí Arsenal ku 'lẹ̀
Ijakulẹ ti ba erongba awọn ọmọ ẹgbẹ Arsenal ati akọni mọọgba wọn Arsene Wenger lati kopa ninu aṣekagba idije Europa league.
Athletico Madrid ṣe adina gbooku fun wọn lati gba ife ẹyẹ naa gẹgẹ bi ami ayẹsi fun Arsene Wenger ti yóò dagbere fun ẹgbẹ Arsenal ni saa ọdun yi.
Ami ayo meji si ọkan lapapọ ni wọn fi pegede lati kopa ninu aṣekagba idije Europa league.
Wenger ní o wù òun láti ka igbá ńlẹ̀ pẹlu Arsenal t'ayọ tìdùnú ṣugbọn ọrọ gbà ọna mìíràn lọ.
Tòun tí wí pé ó ti gba ife ẹyẹ Premiership mẹta àti FA méje, ẹ̀ẹ̀mejì péré ló dé abala aṣekagba ìdíje kánkan tó wáyé ní Yúróòpù lọdun mọkanlelogun tí o kópa fún Arsenal.