Salah ti gbá àmìn ayò mẹ́tàlélógójì s'awọ̀n ní sáà yíí

Lionel Messi

Oríṣun àwòrán, BBC Sport

Àkọlé àwòrán, Akọni ẹlẹ́sẹ̀ ayò ti Barcelona

Njẹ́ a lè fi Salah wé Messi bí?

Salah gbá àmìn ayò méjì s'awọ̀n nígbàtí ẹgbẹ́ Liverpool f'àgbà han AS Roma

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọ̀n olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù ti wòye wí pé, ó séése kí Salah fakọyọ ju Messi lọ lọ́wọ́ yíí.

Mohammed Salah, tó ń gbá bọ́ọ̀lù jẹun fún ikọ̀ Liverpool, ni ọ̀gọ̀rọ̀ èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ó lè gbá bọ́ọ̀lù bí ẹlẹ́sẹ̀ ayò Barcelona, iyẹn, Lionel Messi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Salah gbá àmìn ayò méjì s'awọ̀n nígbà tí ẹgbẹ́ Liverpool f'àgbà han AS Roma pẹ̀lú ayò márùn ún sí méjí nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí ó kángun sí àṣekágbá ìdíje Champions League.

Salah tí ó jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Egypt ni ó ti gbá àmìn ayò mẹ́tàlélógójì s'awọ̀n nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹ́tàdínláàdọ́ta ní sáà yíí nígbà tí Messi tó jẹ́ ọmọ Argentina gbá àmìn ayò ogójì s'awọ̀n

nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ áàdọ́ta.

Látàrí ìdí èyíí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọ̀n olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù ti wòye wí pé ó séése kí Salah fakọyọ ju Messi lọ lọ́wọ́ yíí.