Hanifa Abubakar death: Àwọn afurasí lórí ikú ọmọdébìnrin tó jáde láyé fojú balé ẹjọ́

Ile ẹjọ majistreeti kan nilu Kano ti ni ki wọn fi awọn afurasi ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu iku ọmọdebinrin Hanifa Abubakar si ẹwọn titi di ọjọ keji, ọṣu Keji, ọdun yii.

Awọn afurasi naa ni Abdulmalik Tanko, Hashim Isyaku ati Fatima Musa.

Ṣaaju n wọn ti kọkọ ko awọn afurasi naa lọ sile ẹjọ ọhun lọjọ Aje.

Lẹyin aṣẹ ile ẹjọ naa, kọmiṣọna eto idajọ ipinlẹ ọhun, Musa lawal sọ pe awọn yoo ṣeto iwe ipẹjọ awọn eeyan naa lati gbe wọn lọ sile ẹjọ giga lọjọ mẹrin si asiko yii.

O ni "Awọn agbofinro ti pari iwadii wọn, idi ti a si fi wa sile ẹjọ yii ni pe ki ile ẹjọ naa le fi awọn afurasi naa sinu ọgba ẹwọn titi ti a oo fi ṣe eto ipẹjọ wọn."

"Nitori naa, a oo pe wọn lẹjọ nile ẹjọ giga ni ọjọ merin si asiko yii."

Lati Ọjọbọ to kọja ni awọn afurasi naa ti wa ni ahamọ ọlọpaa ki wọn to gbe wọn lọ sile ẹjọ lọjọ Aje.

Ẹwẹ, kọmiṣọna eto ẹkọ ipinlẹ ọhun, Muhammad Said Kiru sọ pe ijọba ipinlẹ naa ti gbẹsẹle iwe aṣọ idasilẹ gbogbo awọn ile ẹkọ aladani to wa ni ipinlẹ naa titi di igba ti ijọba yoo mọ igbesẹ to kan.

Kiru sọ pe awọn gbe igbesẹ naa nitori bi wọn ṣe ge ẹmi Hanifa kuru, to fi mọ awọn iṣoro mii to n koju eto ẹkọ aladani ni ipinlẹ ọhun.

O ni ile ẹkọ aladani to ba koju oṣunwọn tuntun ti wọn yoo kede ni yoo gba iwe aṣẹ tuntun.

Bawo ni ijinigbe Hanifa ṣe waye?

Ibatan ọmọde naa, Ogbẹni Suraju sọ fun BBC pe Hanifa ma n lọ si ile ẹkọ Keu kan, Dahiru Bauchi Islamic School, ti ko jina si ile wọn.

Oun ati awọn ọmọde yooku ni adugbo si lo jọ ma n lọ, ti wọn tun jọ ma n pada sile awọn obi kaluku wọn.

Suraju sọ pe: "Ni ọjọ Satide, ọjọ kẹrun, oṣu Kejila, ọdun 2021, bi wọn ṣe jade ile Keu ni aago marun-un irọlẹ.

Nigba ti wọn si n pada sile ni ọkunrin kan to wa kẹkẹ ẹlẹsẹmẹrin (Keke Napep) sọ fun awọn ọmọde marun-un naa pe ki wọn wọle ki oun le gbe wọn de ile wọn.

Ibatan naa ni: "Gbogbo wọn ba wọle sinu kẹkẹ rẹ. Bo ṣe wọ inu adgbo wa lo ja awọn mẹrin silẹ, to si sọ fun wọn pe oun fẹ ẹ gbe Hanifa rin kaakiri diẹ ki oun to o gbe pada.

Lati igba naa ni Hanifa ti di awati."

Ẹwẹ, lẹyin ti akara tun sepo ni adari ile ẹkọ naa jẹwọ pe oun loun ji ọmọ naa gbe, ati pe oogun eku ni oun fi gbẹmi rẹ.