Magodo CrisisÀwọn akẹgbẹ́ Gómìnà Sanwo-Olu f'ohùn sílẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdójútini tó ṣẹlẹ̀ sí i lọ́wọ́ ọlọ́pàá ní Magodo

Ohun ti a tun gbọ ni pe awọn Gómìnà akẹgbẹ Sanwo-Olu ni guusu ila oorun Naijiria ti bẹnu àtẹ lú aibọwọ fún ni ti ọlọpaa yi ṣe si Gomina Eko.

Ninu atẹjade taa ri lati ọdọ Gomina Rotimi Akeredolu to jẹ alága awọn Gómìnà naa,o ni iwa abuku gbaa ni ọlọpaa na ju sí Gómìnà to jẹ apàṣẹ waa ipinlẹ Eko.

Akeredolu salaye pe ohun tàwọn ri nínú fidio yi fihàn pé eto ijoba ajumọṣe Federalism ti Nàìjíríà n lo ko ni ìtumọ rara lopin igba ti Gomina ba ni lati beere alaye lori ohun tó n ṣẹlẹ lagbegbe rẹ lọwọ araata.

Nitori naa Akeredolu wa ni awọn bẹnu àtẹ lú iwa aibọwọ f'ẹni yi tawon sì fẹ kí Ọgá ọlọpaa agba salaye ohun to mu ki omo6 iṣẹ rẹ tabuku Gómìnà Eko.

Bẹẹ náà láwọn Gomina bẹnu àtẹ lú agbẹjọro agba ati Minisita feto idajọ ìyẹn Abubakar Malami fun iwa aibikita yi.

Ki l'ohun tó ṣẹlẹ ninu Fidio yi

Lọjọ Ìṣẹgun ni oju opo ayelujara sọ putuputu nigba t'awọn eeyan bẹrẹ sí ni foju ba fidio ti safihan Gomina Sanwo-Olu ati ọlọpaa kan.

Ni Magodo Estate ti wahala kan ti waye lori awọn to ni ile níbẹ ni fiimu yi ti ṣẹlẹ.

Ninu fidio naa a ri ti Sanwo-Olu ti n sọ fún ọlọpaa yi pe ko pe awọn tó ràn wá ṣiṣe pe oun ni ki awọn ọlọpaa kuro ni agbegbe náà.

Ọlópàá yi ni oun kere si ẹni to le pe awọn ọgá rẹ lori ago torí naa oun ko ni le tẹle aṣẹ Gomina.

Fakinfa to waye yi l'ọpọ ṣapejuwe gẹgẹ bí aibọwọ fún Gomina to ni ko yẹ ki ọlọpaa wa lati Abuja lati wa dasi ọrọ aabo lai fi to ohun leti.

Igba akọkọ kọ ni yi ti iru iṣẹlẹ k'awọn agbofinro ma fi ọwọ fun Gomina nipinlẹ nitori pe lọdọ ìjọba àpapọ ní wọn l'awọn ti n gba aṣẹ.

Ni pàápàá àwọn ọlọpaa tabi ọmọ ogun kii tẹle aṣẹ mi yatọ sí eleyi ti wọn ba fún wọn láti ọdọ awọn alaṣẹ ìjọba àpapọ bi ọgá àgbà ọlọpaa, ileesẹ ologun tabi Minisita feto idajọ.