You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹlẹ́wọ̀n méjì kú, wọ́dà farapa lásìkò tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n fẹ́ sálọ ní Ile-Ife
Iroyin sọ pe ẹlẹwọn mẹrin lo kú lọjọ Iṣẹgun, ni ọgba ẹwọn to wa ni agbegbe Kosere nilu Ile-Ife nipinlẹ Osun.
Eyi waye lasiko ti awọn ẹlẹwọn kan n gbiyanju lati salọ kuro ni ọgba ẹwọn.
Iroyin sọ pe ni owurọ ọjọ Iṣẹgun lasiko ti awọn ẹlẹwọn n tun ayika ọgba ẹwọn sẹ, ni awọn kan lara wọn gbiyanju lati salọ.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn ni Naijiria sọ fun BBC pe awọn ẹlẹwọn naa pa alamojuto wọn kan lara, amọ awọn eleto aabo ri wọn da duro ki wọn o to o jade.
- Adigunjalè kọlu Kemi Afolabi, wọ́n fi àdá ṣá òun àti awakọ̀ rẹ̀
- Ká má rí! Kò sí aàyè fún ìdìbò Gómìnà ní Osun àti Ekiti- Ilana Omo Oodua
- IPOB fòfin dè kíkọ orin ògo Nàìjíría láwọn ilé ẹ̀kọ́ gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà nítorí pé...
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ Wasiu Eluyẹra tó fẹ́ pa ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó lóyún
- Ọmọkùnrin kan bẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tó lóyún lórí nítorí pé...
Lasiko naa ni awọn oṣiṣẹ alaabo yinbọn mọ mẹrin lara wọn. Eyi to mu ki awọn yooku sa pada nigba ti wọn ri pe ọwọ ti tẹ awọn adari wọn.
Wọn gbe wọn lọ sile iwosan, ṣugbọn meji lara wọn pada kú.
O ti to ìgbà mejila laarin ọdun meji, ti awọn ẹlẹwọn ti gbiyanju lati sa lọ jakejade Naijiria. Ogunlọgọ wọn lo si raaye salọ.