You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
e-Naira: CBN ní ó le ni eniyan 5000 to ti gba ojú òpó e-Naira lórí ayélujára lẹyìn ọjọ́ kan tí wọn ṣèfilọ́lẹ̀ rẹ̀
Banki apapọ Naijiria, CBN ti ni owo Naira Naijiria ti kii se beba amọ to jẹ ori ẹrọ ayelujara, eNaira ti wa ni ikalẹ fun awọn eniyan lati lo bayii.
CBN ni eNaira naa ni yoo jẹ akọkọ ni ilẹ adulawọ, ti wọn yoo ti le na lori ẹrọ ayelujara.
Bakan naa ni igba akọkọ ni yii ti orilẹede Naijiria yoo ni owo tii kii se beba, ti wọn si le e na lori ẹrọ ayelujara lati fi ṣe karakata.
Ọjọ Karundinlọgbọn, Oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 ni Aarẹ Buhari ṣe ifilọlẹ e-Naira naa nilu Abuja.
Ọna ti a le gba na e-Naira ree ati bo ṣe rọrun si:
• Apo owo eNaira Wallet naa ni eNaira wa ni ibi ti ''ledger'' wa ti yoo ma sọ bi owo ṣe n wọle ati bi o ṣe n jade.
• CBN ni o ti le ni ẹgbẹrun marun un eniyan to ti ''download'' eNaira naa lori Google Play Store ati Apple Store, ni kia ti wọn ṣe ifilọlẹ rẹ.
• Awọn banki ni lẹyin oṣu mẹta ti wọn ṣe ifilọlẹ rẹ ni awọn yoo to bẹrẹ si ni yọ owo ''charges'' lori rẹ.
• Awọn owo ti wọn ba n fi si apo eNaira wallet naa ni wọn yoo ma lo lati fi gba owo ati san owo fun awọn eniyan.
• Iye kan naa ni eNaira ati Naira fun'ra rẹ jẹ, iyatọ kan ni pe ori ayelujara nikan ni wọn ti le e na eNaira kii ṣe ''paper.''
• Bakan naa ni wọn le e fi ṣe karakata pẹlu owo ilẹ okeere USSD lai si ifoya.
• Awọn ile ifowopamọsi ni ti won ba lo eNaira lati fi ''send'' owo si eniyan; Kiakia ni ẹni naa yoo ri i gba a
• Igba gbogbo ni iṣẹ rẹ yoo ma a lọ , ko ni si idaduro lẹnu iṣẹ
• Binti ni ''charges'' ori rẹ.
• Gbogbo ibi ni Naijiria ni wọn ti le gba owo eNaira naa.
• Ko ni si pe wọn n jini lowo gbe lọ lori ẹrọ ayelujara.
Idi ti CBN se gbe eNaira kalẹ:
• Yoo jẹ irọrun fun ẹka ọrọ aje lorilẹede Naijiria.
• Ko ni si inira pẹlu karakata lori ẹrọ ayelujara pẹlu lilo eNaira.
• Yoo ran banki lọwọ lati le e gba owo ori labẹle, ti yoo mu ilu gbooro si.
• Ko si apa ibi kankan ni Naijiria ti wọn ko ni ti le e san owo yii.
• CBN ni wọn le ''download'' eNaira naa lori Google Play Store ati Apple App Store bayii.