Senate on bandits: Ilé àṣofin, Afenifere àti Arewa ní kí Buhari kéde agbébọn bíi afẹ̀miṣòfò

Ẹgbẹ Afenifere ati Arewa Consultative Forum ti pa ẹnu pọ kin ọrọ awọn sẹnẹtọ ti wọn sọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari pe ki o bẹrẹ si ni ri awọn janduku agbebọn ni agbesunmọmi.

Eekan Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo sọ fun BBC Yoruba pe ẹgbẹ naa ti n sọrọ yii fun Buhari tipẹ, amọ o kọ eti ikun.

Oloye Adebanjo ni awọn Miyetti Allah gan an lo yẹ ki Buhari pe ni agbesunmọmi dipo ẹgbẹ IPOB ti ijọba rẹ pe ni agbesunmọmi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

``Baba Adebanjo ni igbayii laarọ awọn sẹnẹtọ lori ọrọ ti wọn sọ fun Buhari, amọ Oloye Afenifere ni o ba ni, ko bajẹ.

Oloye Adebanjo ni ijọba Buhari ko tii wa nkan ṣe si gbogbo ọrọ tawọn eeyan kan ti sọ lori eto abo mẹhẹ ni Naijiria.

''Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom ti lọ ba Buhari lori iṣẹlẹ iṣekupani to n waye ni Benue, ohun ti BUhari maa sọ fun ni pe ki o lọ bawọn alabagbe rẹ ṣọrẹ.

Ajagun fẹyinti, Commodore Kunle Olawunmi sọ lori ẹrọ amohunmaworan Channels TV pe awọn gomina, minisita, sẹnẹtọ atawọn to n ṣe pasi paarọ owo wa lara awọn to n ṣe atilẹyin fun Boko Haram.

O tun fi idi rẹ mulẹ pe ijọba Buhari mọ nipa ọrọ naa lai ṣe ohun kan lori ọrọ naa.

O dabi ẹni pe ohun tawọn agbebọn yii n ṣe ko kọ Buhari lominu ni ko ṣe gbe igbesẹ akin lori ọrọ naa.

Nnkan ti bajẹ ju bo se yẹ lọ laye Buhari - Arewa

Ẹwẹ, akọwe iroyin ẹgbẹ Arewa Consultative Forum(ACF), Emmanuel Yawe sọ fun BBC Yoruba pe ti orukọ to ba buru ju agbesunmọmi lọ ba wa, ohun lo yẹ ki Buhari pe awọn agbebọn afẹmi ṣofo yii.

Yawe ni ẹgbẹ ACF naa ti n sọ ti pẹ agbesunmọmi lawọn janduku ajinigbe ati afẹmi ṣofo yii pẹlu iṣẹ laabi ti wọn n ṣe kaakiri ni Naijiria.

Akọwe iroyin ẹgbẹ ACF ni awọn ni ijakulẹ ninu Buhari tori awọn ro pe oun ni yoo ṣe atunṣe gbogbo ohun to ti bajẹ ni Naijiria.

Ṣugbọn Yawe ni o ṣeni laanu pe nkan ti bajẹ ju bi o ti wa tẹlẹ laye aarẹ ana Goodluck Jonathan gan an lọ bayii.

Yawe ni ko si ohun to buru ninu ohun tawọn sẹnẹtọ sọ fun Buhari pe ko bẹrẹ si ni ri awọn agbebọn yii gẹgẹ bi agbesunmọmi.

Ilé àṣofin ké sí Ààrẹ Buhari láti kéde àwọn agbébọn gẹ́gẹ́ bí jàǹdùkù afẹ̀miṣòfò

Ile aṣofin agba ni Naijiria ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko kede awọn janduku agbebọn gẹgẹ bi agbesunmọmi ni kiakia.

Nibi ijoko ile to waye ni Ọjọru ni awọn sẹnetọ naa ti sọ ọrọ yii.

Bakan naa ni awọn aṣofin sọ pe ko tun kede gbogbo olori awọn agbebọn naa ti ijọba mọ gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa, ko si tọpinpin ibi ti wọn wa lati fi ofin mu wọn fun igbẹjọ.

Wọn tun sọ pe ki Aarẹ Buhari paṣẹ pe ki awọn ọmọ ogun ju ado oloro si ibuba awọn agbebọn naa.

Ijiroro ọhun waye lẹyin ti aṣofin kan lati ipinlẹ Sokoto, Ibrahim Gobir gbe aba kan kalẹ lori eto abo.

Eyi waye lẹyin ọjọ kan ti awọn agbebọn pa eeyan to to ogún, ti wọn si tun ji awọn kan gba lọ ni abule Gatawa, nijọba ibilẹ Sabon Birni nipinlẹ Sokoto.

Bakan naa, awn wọnyii o ṣẹṣẹ maa da ẹmi awọn eeyan Naijiria legbodo paapaa lapa Ariwa.

Ṣaaju ni ikọlu kan ti waye ni abule Gangara, nijọba ibilẹ kan naa.

Ninu ọrọ to sọ, Aarẹ ile aṣofin, Sẹnetọ Ahmad Lawan pe fun fifi kun owo ti ijọba n na sori iṣẹ awọn ọmọ ologun.

O si sọ pe o ti di dandan fun awọn igbimọ nile aṣofin to wa fun eto aabo, lati ri i daju pe wọn n na owo awọn ileeṣẹ ologun fun nkan to yẹ.