You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho latest news: Àwa àgbààgbà Yorùbá kò fi ọwọ́ sí ìdásìlẹ̀ Oduduwa Nation - YCE
Akọwe fun ẹgbẹ awọn agbaagba ilẹ Yoruba, Dokita Kunle Olajide ti sọ pe awọn ko fi ara mọ ijijagbara fun orilẹ-ede Oduduwa, to n waye.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, o ni ẹya Yoruba ti jiya pupọ fun orilẹ-ede Naijiria, paapaa lori ọrọ ominira kuro lọwọ amunisin, ati lẹyin to gba ominira tan.
Lẹyin naa lo tun tọka si ipa ti Yoruba ko ninu ogun abẹle Biafra to waye.
O ni Yoruba ni igbagbọ pe orilẹ-ede Naijiria ṣi ma a dara laipẹ
O ni lootọ ni nkan ko lọ bo ṣe yẹ ko lọ, paapaa lati bi ọdun marun ti ijọba to wa nibẹ bayii ti gun ori aleefa.
- Ọ̀rọ̀ òṣèlú ni bí Akeredolu ṣe tako ìdásílẹ̀ Oduduwa Nation - Banji Akintoye
- Bàbá ni Alake Ẹgba jẹ́ fún mi, mi ò lè ṣe ìkọlù sí ààfin rẹ̀ - Igboho
- Àwọn ọ̀dọ́ Ibarapa yabo ọọ́físì Seyi Makinde lórí ètò àbò tó mẹ́hẹ
- Kò sí Oduduwa Nation kankan ni ilẹ̀ Iwo! Kí n má gbọ́ ọ - Oluwo
- Bí òkú ṣe máa ń bàjẹ́ ní Mọ́ṣúárì tẹ́ẹ ò bá san owó ìtọ́jú fáwọn olùtọ́jú òkú rèé
"Lati igba ti mo ti de aye, ko si asiko ti ija ẹlẹyamẹya ati ẹsin pọ ni Naijiria buru to bo ṣe ri bayi. Bakan naa ni ọrọ abo.
"O fojuhan pe ijọba naa fi si apa kan."
O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe awọn ko ti i ṣetan lati lọ si ibi kankan, pe ko rọrun bẹẹ, "nitori pe a ti wa papọ, o ti le ni ọgọrun ọdun".
O ni ṣaaju ki awọn oyinbo to de ni ibaṣepọ ti wa laarin awọn ẹya to parapọ di Naijiria.
"Awọn ọdọ to n binu ni ẹtọ lati binu, nitori pe wọn n ja fun ọjọ ọla wọn ni.
Ṣugbọn awa agbagba n sọ pe ko yẹ ki wọn tẹ ẹ jẹjẹ, nitori pe ọmọ ọdọ naa ma an fi ọgbọn ṣe."
"A ni ki wọn o rọra, nitori pe a ko ni i fẹ ki ogun abẹle kankan ti ọdọ Yoruba bẹrẹ.
O ni ayafi to ba jẹ pe aarẹ deedee sọrọ lọjọ kan pe ki kaluku ma a ba tiẹ lọ.
"Awa naa ṣetan. ṣugbọn kii ṣe ki a doju ija kọ ijọba Naijiria nitori pe kaakiri Naijiria ni awọn ọmọ Yoruba wa.
Ka fi suuru yanju rẹ ni awa agbaagba n sọ."