You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àgbàrá òjò gbé alága àdúgbò àti èèyàn méjì mìí lọ nílùú Ibadan
Agbara ojo gbe alaga adugbo ati awọn eeyan meji mii lọ nilu Ibadan.
Ọfọ nla ṣe ni adugbo Oke-Odo to n bẹ ni agbegbe Igisogba Omo-Adio ilu Ibadan nibi ti agbara ojo ti gbe alaga adugbo naa ati awọn eeyan meji mii lọ lọjọ Aje.
Atẹjade ti ileeṣẹ igbohun safẹfẹ Double A Media fi lede lo fi idi ọrọ mulẹ pe arọda ojo lo ṣokunfa iṣẹlẹ laabi naa.
Meji ninu awọn olugbe agbegbe naa to ba awọn oniroyin sọrọ Arakunrin Alimi Olumuyiwa ati Wasiu Adeshina ṣe alaye wi pe eeyan mẹta ọtọọtọ lo ri sinu agbara ojo lọjọ Aje.
Lara wọn ni alaga adugbo naa, Arakunrin Nureni Adejumo ti gbogbo eeyan mọ si "Master" wa.
Siwaju sii, ọmọ alaga naa Onimọẹrọ Nurudeen Adejumo sọ fun awọn oniroyin pe oun gba ipe pajawiri ni irọlẹ ọjọ naa wi pe agbara ojo ti gbe baba oun lọ ti o si ti di awati bayii.
O tẹsiwaju wi pe ohun ibanujẹ nla gbaa ni iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi o ṣe n mu un wa si iranti wi pe aibikita ijọba naa lo ṣekupa iya oun ni nnkan bi i ọdun mẹwa sẹyin.
Nibayii gbogbo awọn olugbe agbegbe naa ti rawọ ẹbẹ si gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde lati dide iranlọwọ lori afara kan to nilo atunṣe ni agbegbe naa lati bi i ọdun mẹwa sẹyin ki iru iṣẹlẹ bẹẹ ma baa waye mọ.