You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Alleged murder: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ẹ̀gbọ́n tó dáná sun àbúrò rẹ̀ toyúntoyún nílùú Eko
Victoria ẹni ogún ọdún, ni wọ́n ní ó ti kú toyúntoyún lẹ́yìn tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ dáná sun-ún lágbègbè okokomaikoko níjọba ìbílẹ̀ Ojo nípìnlẹ̀ Eko.
Ìròyìn ní Victoria gbẹ́mì mì lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tó ní ìyá àwọn lo ní kí òun bawí nítorí ìwà àgbèrè to n hù, dáná sun-ún.
Ẹ̀gbọ́n Victoria ló gbé epo bẹtiróò ni sọ́ọ̀bù tí wọ́n tí n ta oúnjẹ ló bá sọná sábùrò rẹ̀ lára.
- Àntí Korona ni wọ́n n pè mí l'ádùúgbò láti ìgbà tí mo ti ní Covid-19- Motosinoluwa Afolaranmi
- Ilé ẹjọ́ dá Ààfá dúró láti gbé ọmọ ọdun 16 sílé gẹ̀gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀ kẹ́sàn án
- Òṣèré tíátà, Ọmọba Femi Oyewunmi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Laditi ti jáde láyé
- Ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti mọ òkodoro bí wọ́n ṣe gbé ọmọ tuntun náà sin láàyè ní India
- Arákùnrin tó jí Ese Oruru gbé ti rí ẹ̀wọ̀n ọdún 26 he
Ọ̀pọ̀ ní àwọn kò lè sọ ní pàtó ẹ̀sẹ̀ ọmọbìnrin náà, ṣùgbọ́n àwọn kan ní o fọ́ ìyá rẹ̀ létí lásìkò tí wọ́n ní gbólóhùn asọ̀.
Nígbà tí àwọn míràn ní, ẹ̀gbọ́n àti ìyá n bá a Victoria wí nítorí pé o ti fi ilé sílẹ̀ láti bí ọ́jọ́ mẹrin tó lọ n sùn ti àwọn ọkùnrin káàkiri.
Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀ tí wọ́n gbìyànjú títí láti pa iná náà, ẹ̀pa ò bóró mọ́, gbogbo ìgbìyànjú láti gbé lọ sí ilé ìwòsàn lo já sí pàbó nítorí pé o ti jóná kọjá àlà tí ọ̀pọ̀ ko sì le dìde ìrànwọ́.
Lẹ́yìnòrẹ̀yìn tí wọ́n tún rí gbé dé ilé ìwòsàn aládàni, àwọn dókítà ibẹ̀ ni kí wọ́n máa gbé e lọ Alimoso General Hospital fún ìtọ́jú tó péye.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn aládùúgbò ṣe sọ, ilé ìwòsàn ni wọ́n ti sọ fún wọ́n pé ó ti jóná kọjá àfẹnusọ, àti pé kò sí àtúnṣe mọ́ láti dóòlà ẹ̀mí rẹ̀.
Ìwé ìròyìn Guild sọ pé ẹ̀gbọ́n Victoria tó ṣiṣẹ́ yìí ti kọ́kọ́ na pápá bora bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ṣẹ̀, kí àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò tó wa jáde tí wọ́n sì fà á lé ọlọ́pàá lọ́wọ́ ni agbègbè Okokomaiko fún ìgbéjọ́ tó yẹ
Agbẹnusọ ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ Eko Bala Elikana ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni pé ẹ̀gbọ́n ọmọbìnrin náà ló dáná sun-ún.
Bala fi kún un pé ẹjọ́ náà ti wà níwájú ẹ̀ka tó n rí sí ìwà ọ̀daràn ni Panti Yaba fún ìwádìí tó péye lórí ọ̀rọ̀ náà tí yóò sì fojú balé ẹjọ́ ní kòpẹ́kòpẹ́.
"Ẹgbọ́n rẹ̀ ló dáná sun-ún, o ni àbúrò òun kò bọ̀wọ̀ fún ìyá àwọn tó nítorí rẹ̀ sì ni oun ṣe dáná sun-ún láti bá a wí.
" Ìyá wọ́n naa farapa lásìkò tó n gbìyànjú láti paná lára ọmọ.
A o gbé ọ̀daràn naa lọ ilé ejọ́ ni kété tí a ba ti parí ìwádìí tiwa nítorí àti gbà a kúrò lọ́wọ́ àgọ́ ọlọ́pàá okokomaiko, lọ sí Panti ni Yaba, yóò sì fojú balé ẹjọ́.