You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus in Nigeria: Ọmọ Nàìjíríà 292 láti Saudi Arabia gúnlẹ̀ sí Abuja
Ọdunrun o din mẹjọ lawọn ọmọ orilẹede Naijiria to gunlẹ si ilu Abuja lati orilẹede Saudi Arabia lalẹ ọjọ Iṣẹgun.
Minisita fọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria, Geoffrey Onyeama lo fi idi ọrọ yii mulẹ loju opo twitter rẹ lọjọru.
O ni pupọ lara awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn ko wale naa ni wọn jẹ obinrin to n tọ ọmọ lọwọ atawọn ọmọde. O fi kun un pe wọn ti fi wọn si ipamọ lawọn ileetura labẹ amojuto ajọ to n dena ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC.
Minisita Geoffery Onyeama ṣalaye pe ijọba orilẹede Saudi Arabia lo ṣe atọna bi awọn eeyan naa ṣe de orilẹede Naijiria.
Bakan naa lo sọrọ lori awọn ọmọ Naijiria kan to n kẹkọ lorilẹede Malaysia to si ni ijọba apapọ ko tii gbọ iroyin pe wọn fẹ le awọn akẹkọ naa nitori pe iye ọjọ to wa lori iwe igbelu wọn ti pe.
Awọn kan lo kan si ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria pe ẹgbẹrun mẹtala lawọn ọmọ orilẹede Naijiria to n kẹkọ ni Malaysia, ṣugbọn ti o ṣeeṣe ki ijọba orilẹede naa o fi tipatipa da pada sile nitori iye ọjọ to wa lori iwe igbelu wọn ti ko.