Coronavirus protest: Àwọn Dókítà fáríga nípìnlẹ̀ Ondo,wọn ní kí Gomina san owó oṣù mẹ́ta tó jẹ wọ́n!

Àwọn agbarijo pò dokika ni ile ise ìwòsàn tí ilé ìwé àwọn dókítà ni Ipinle Ondo (UNIMED) ni wọn ti fi ehonu wọn lónìí ní bí ijoba Akeredolu kò ti ṣe san owó oṣù wọn láti bíi oṣù merin àbọ̀ seyin.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ nígbà tí ó ń bá àwọn akoroyin sọ̀rọ̀, Dókítà, Taiwo Olagbe, tí ó jẹ ọkan lára àwọn dókítà náà ṣàlàyé pé, ijoba ipinle Ondo pá wọn ti nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ń koju bíbá aarun Corona ń fínra nípa titoju àwọn tí ó fara kaasa aarun náà.

Ó tesiwaju pé, pupọ nínú wọn ni kò lè san owó ilé mọ, tí wọn kò sì lè rà epo sì moto lọ sí ibise.

Bayii, àwọn dókítà náà tí tẹpẹlẹ mọ pe, àwọn yóò dá ìṣe silẹ tí ìjọba kò bá dasi owó wọn ní sísan.

Kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá kó gbogbo ọlọ́pàá ẹkùn Ondo lọ fún àyẹ̀wò COVID-19

Lẹyin ti ayẹwo fihan pe ọlọpaa mẹta ko arun coronavirus ni ipinlẹ Ondo, kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Undie Adie paṣẹ pe ki wọn ko gbogbo ọlọpaa to wa ni ileeṣẹ ọlọpaa Yaba division ni ilu Ondo lọ fun ayẹwo arun COVID-19 lẹyẹ o ṣọka.

Iroyin ti a gbọ ni pe awọn ọlọpaa ẹkun naa ti kọkọ faake kọri pe awọn ko ni ayẹwo kankan lati ṣe.

Amọṣa, ọga ọlọpaa naa ti ni nibi ti ọrọ de duro bayii, ilu Akurẹ gan an ni ki wọn ko gbogbo wọn wa si fun ayẹwo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, ASP Tee-Leo Ikoro ṣalaye fun BBC News Yoruba pe gbogbo awọn ọlọpaa ẹkun naa ni wọn ti ṣe ayẹwo fun lai da eeyan kan si ti wọn si n reti esi ayẹwo wọn bayii.

"Gbogbo wọn ni wọn ṣe ayẹwo ti a si n reti esi ayẹwo wọn lẹyin sjs marun un nitori lẹyin ọjọ marun un ni wọn sọ fun wa pe esi ayẹwo wọn yoo jade".

O fi kun un pe wọn ti paṣẹ fun gbogbo awọn ọlọpaa ẹkun naa lati lọ ya ara wọn sọts ni ile titi di igba ti esi ayẹwo wọn yoo fi jade.

Ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Undie Adie ṣalaye ṣaaju pe, "mo ti paṣẹ fun wọn pe ki wọn wa fun ayẹwo ni ilu Akurẹ, a ni lati ṣọra gidigidi ki a maa baa ri ajakalẹ arun nileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ yii".

Kọmiṣọna ọlọpaa naa tun paṣẹ ki wọn ko awọn mọlẹbi wọn ati gbogbo awọn eeyan ti wọn ti ba pade lẹnu ọjọ mẹta yii dani pẹlu.

Nigba ti BBC News Yoruba ṣe ayẹwo nipa ileeṣẹ ọlọpaa ti awọn naa ti n ṣiṣẹ, awọn aladugbo ni awọn ọlọpaa ṣi n ṣiṣẹ ni ibẹ.

Amọṣa alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe ni ipele-ipele ni wọn fẹ ṣeto ayẹwo naa ati pe niwọn igba ti ileeṣẹ ọlọpaa ko lee wa ni titipa ni wọn ṣ n ṣe ni ipele.

O fi kun pe nigba ti esi awọn lpaa naa ba jade lawn yooku yoo tun l ṣe e.

Uniport: Àwọn ọlọ́pàá wú òkú akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Uniport mẹ́ta tí àwọn ajínigbé sin

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers ti wu oku akẹkọọ Fasiti ilu Port Harcourt mẹta jade lọjọ Ẹti: meji jẹ ọkunrin, ẹnikan si jẹ obinrin.

Ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun 2020 ni awọn ajinigbe gbe awọn akẹkọọ naa, Nelson Nwafor, Fortune Obemba ati Joy Adoki, nilu Choba to jẹ ọẹan lara awọn ilu to yii fasiti naa ka. Ṣugbọn ọwọ ọlọpaa tẹ afurasi mẹta lọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2020, gẹgẹ bi nkan ti wọn sọ fun BBC.

Ọkan lara awọn afurasi tọwọ tẹ, Friday Akpan, lo mu awọn ọlọpaa lọ si ibi ti wọn ti wu awọn oku naa jade ninu iboji kotopo kan ti wọn sin wọn si ninu igbo ladugbo Eleme, lọjọ kinni, oṣu Karun, ọdun 2020.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, Akpan jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni oun, awọn si ti ji awọn eeyan gbe lẹẹmeji.

Akpan sọ pe ọkan lara awọn adari ẹgbẹ naa, Bright, lo ji awọn akẹkọọ to ti d'oloogbe "nitori pe ọkan lara wọn dalẹ oun lasiko ti owo kan wọ akanti rẹ, ṣugbọn ti ko ko o silẹ f'oun".

Eyi lo si mu ko ranṣẹ pe Akpan ati awọn yooku rẹ lati gbe wọn lọ ọ pa sinu igbo.

Akpan sọ fun awọn ọlọpaa pe Bright lo paṣẹ pe ki wọn o pa wọn.

Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Joseph Mukan sọ pe ki awọn ẹbi awọn oloogbe o ma bẹru, nitori pe awọn yoo ri pe idajọ ododo fẹsẹmulẹ.

Kii ṣe igba akọkọ niyi ti iru iṣẹlẹ bayii ti waye ni ipinlẹ Rivers.

Awọn ọlọpaa wu oku ọmọbinrin kan, Ozigie Wovueze jade loṣu Kejila, ọdun 2018, ninu yaara ọrẹkunrin rẹ, Ndema Owabie lagbegbe Rumuepirikom.

Bakan naa ni wọn yọ oku obinrin kan, Charity Ohaka, ti awọn to pa a ju sinu kanga kan ni Rumuosi.

Awọn kan naa pa oṣiṣẹ ile itaja itakun agbaye Jumia lọdun mẹta sẹyin, ti wọn si ju oku rẹ sinu ile iyagbẹ.

Ẹjọ naa ṣi wa nile ẹjọ.