MRKH syndrome: 'Ọjọ́ lọjọ́ tí mo mọ̀ pé wọ́n bí mi láì ní ojú ara obìnrin àti ilé ọmọ'

Ibeere kan ti dokita rẹ bi i nipa nkan oṣu lo jẹ ki Julian Peter to ti pe ẹni ọdun mọkandinlọgbọn o mọ pe wọn ko bi oun pẹlu ile ọmọ, ẹnu ọna ile ọmọ, ati oju ara obinrin.

Lẹyin ọdun mejila to mọ nipa ailera rẹ yii lo sọ itan igbesi aye rẹ fun BBC.

"Wọn bi mi pẹlu ipenija ilera kan ti wọn n pe ni Mayer-Rokitansky-Kusher-Hauser syndrome (MRKH).

Ailera yii tumọ si pe ẹni naa ko ni i ni ile ọmọ, tabi oju ara obinrin, o si tun le jẹ kindinrin kan pere ni iru ẹni bẹ yoo ni.

Obinrin to ba ni MRKH kii ṣe nkan oṣu.

Igba ti mo wa ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni mo ri i pe mo ni ailera ni ẹsẹ mi i, nitori pe gbogbo igba lo maa n wu.

Nkan akọkọ ti dokita kọkọ beere lọwọ mi ni pe igba wo ni mo ṣe nkan oṣu kẹhin. Ṣe emi ti mi o mọ bi nkan oṣu ṣe n ri?

Wọn ya aworan (scan), iyẹn si fihan pe mi ko ni ile ọmọ tabi oju ara obinrin. Ibẹ si ni wọn ti sọ pe mo ni ailera MRKH.

Mo sun ṣege ẹkun lọjọ akọkọ, ọjọ keji ati ọjọ kẹta, ki n to o gba kamu.

Ọmọde ṣi ni mi, ọmọ ọdun mẹtadinlogun. Nkan to si wa ni ọkan mi ni bi maa ṣe pada sileewe.

Iya a mi tẹle mi lọ si ileewosan, nkan ti dokita si sọ fun ba a l'ẹru.

Ọpọlọpọ ibeere lo wa ni ọkan rẹ lati beere.

Lo ba bẹrẹ si ni ro o pe ta a ni oun ṣẹ to fi iru nkan bẹ kan ọmọ oun.

'Nkan to ba wu ẹlẹnu ni ko fẹnu rẹ sọ, fila ma wo ibẹ ni mo de'

Ẹnikan tilẹ sọ fun mi pe ki n lọ si ibi ti wọn yoo ti gbadura fun mi.

Ẹlomiran sọ pe aye mi ri bẹ nitori ibi ti mo ti wa, Ukambani (agbegbe kan ti wọn sọ pe awọn ajẹ wa).

Awọn miran sọ pe iya-iya mi lo wa nidi ọrọ mi.

Wọn le sọ nkan to ba wu wọn. Nkan to ṣe koko ni ipa to ni lara mi.

To ba jẹ pe mo feti si ti wọn ni, mi o ba ti maa ro pe otitọ ni nkan ti wọn n sọ.

'Mi o kọkọ fẹ ẹ ṣe iṣẹ abẹ naa'

Nitori pe mo ti kọ ẹkọ nipa ẹya ara tẹlẹ, oye nkan ti dokita sọ nigba akọkọ ye mi.

Mo sọ fun iya mi pe mi o ti i ṣetan lati ṣe iṣẹ abẹ, nitori pe mo kọkọ fẹ ẹ pari ẹkọ mi.

Ọdun mẹwa lẹyin rẹ, mo lọ sileewosan naa, wọn ṣe iṣẹ abẹ fun mi, o ṣi yọri sirere.

Iru ailera MRKH ti mo ni tumọ si pe mi ko ni oju ara obinrin, ile ọmọ, ati pe kindinrin kan ṣoṣo ni mo ni.

Igbaye mi ri boṣeyẹ ko ri, nitori pe aarun naa ko ni ipa lori bi mo ṣe fẹ gbe igba-aye mi.

Ṣugbọn fun awọn eniyan kan, o maa n ba wọn ni ọkan jẹ, wọn si gbọdọ ri awọn akọṣẹmọṣẹ to le ranwọn lọwọ lati gba kadara lori aarun naa.

Ti o ba ni oye ipa ti aarun naa n ni ni ara, o ko ni yọ ara rẹ lẹnu pe o fẹ ẹ bimọ.

Mo ti ya fọto ara (scan) lẹẹmẹrin, wọn ko si ri ọpa to n gbe ẹyin lọ sile ọmọ, pe boya wọn le ri ẹyin ọmọ lati lo ilana igbalode IVF, fun mi ki n le di ọlọmọ,ṣugbọn ko ṣe e ṣe.

Mi mọ pe o ko dabi awọn obinrin yooku jẹ ọgbẹ ọkan, ṣugbọn o kan nilo lati gba bẹ, ki o si wa ẹni ti o le fi ọrọ lọ.

Mo ti ṣalabapade ọpọ eniyan ni Kenya yii to ni iru aarun yii, a si n sọ iriri wa fun'ra wa. Mo ti gba kadara tipẹ-tipẹ.

Sisọ fun awọn ololufẹ mi

Mo ti rinrinajo ifẹ lọpọlọpọ. Ṣugbọn, mi o ki n jẹ ko pẹ ti mo ti maa n jẹ ki ẹni naa o mọ nkan ti mo n ba a finra.

Ti wọn ba fẹ ẹ gba, wọn a gba. Ṣugbọn, ṣe ẹyin naa mọ pe eniyan ẹlẹran ara naa ni eniyan yoo ma a jẹ.

Ọpọlọpọ awọn ti mo sọ fun fimi silẹ. Awọn kan ti ẹ sọ pe irọ ni mo n pa, pe ọna lati le awọn lọ ni mo ṣe sọ bẹ ẹ.

Lọwọlọwọ, mi ko ni ololufẹ kankan.

To ba jẹ tori ibalopọ ni, mo ṣe iṣẹ abẹ l'ọdun 2018, eyi ti yoo mu ki o ṣeeṣe fun mi.

Ṣugbọn, mi o ti i ṣetan lati ni ibalopọ, mi o si ṣetan lati ṣegbeyawo.

Ti asiko ba to, a o gba ọmọ tọ.

O gba mi to ọdun mẹwaa ki n to pinnu lati sọ ọrọ aye mi sita.

Awọn eniyan wa ti ko mọ nipa MRKH, mo fẹ ẹ polongo faraye.