You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Police: Aago méjìlá òru ní afurasí náà bẹ́ sí ọ̀sà àmọ́ kò kú
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tu aṣiri sita pe ọkunrin kan, Princewill David to bẹ sinu odo ọsa latori afara Third Mainland laipẹ yii, pa ọrẹbinrin rẹ lo fi ṣe bẹ ẹ.
Oṣu to kọja ni iroyin jade pe ọkunrin naa pe ọkan lara awọn takisi igbalode Uber pe, ko gbe oun lọ si adugbo Lekki ni Lagos Island, to si wọ ọkọ naa lati ile rẹ ni adugbo Igando.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kò sẹ́ni tó fẹ́ pa Buhari o, ọkùnrin tó pakuru mọ́ ààrẹ kàn fẹ́ bọ̀ọ́ lọ́wọ́ ni - Femi Adesina
- Yorùbá rẹwà, kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ìró ẹnu wọn jọra àmọ́ tí ìtumọ̀ wọn yàtọ̀
- Àríwá Nàíjíríà, ẹ sọ ẹran jọ̀bọ̀-jọbọ nù pẹ̀lú Sanusi tẹ yọ lóyè - Soyinka gbarata
- Coronavirus tún ti bẹ́ gìjà sí Ghana àti Gabon
- Ẹ yọmí kúrò ní àhámọ́! Sanusi pe Ọ̀gá ọlọ́pàá àti Ọ̀gá DSS lẹ́jọ́
Iroyin sọ pe ki ni wọn de ori afara Third Mainland si ni nkan bi aago mejila oru, ni David sọ fun awakọ Uber naa pe ko duro fun oun lati tọ.
Ṣugbọn kaka ki awakọ naa duro fun, n ṣe lo wa a lọ si ibi ti ikọ awọn ọlọpaa pajawiri, Rapid Response Squard, duro si ni ori afara naa, lati pe akiyesi wọn si ọrọ naa.
Awakọ yii ṣe bẹẹ nitori pe o gbọ nipa ọdọmọkunrin kan, Toju Daibo, to lo iru ọgbọn bẹẹ lati bẹ sinu odo lati ori afara yii bakan naa, lẹyin to sọ fun awakọ takisi to gbe e pe, oun fẹ tọ.
Ṣugbọn ko to o ṣalaye fun awọn ọlọpaa naa, David ti sa jade ninu takisi, o si bẹ sinu odo ọsa.
Amọ ọrọ gba ibomiran yọ fun nitori pe ori awọn igi nla to wa lori omi naa labẹ afara lo jabọ le, ki awọn ọlọpaa RRS, ọlọpaa ori omi ati awọn to mọ odo wẹ to doola rẹ.
Kọmisana ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, sọ fun awọn akọroyin, lasiko to n fi oju awọn afurasi ọdaran kan han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa lagbegbe Ikeja pe, David ati ọrẹbinrin rẹ ti wọn ko ti mọ ohunkohun nipa rẹ, lo jọ ja, ti David si pa a lasiko ija naa ni ile itura kan.
Lẹyin naa lo wọkọ lọ si afara Third Mainland lati gbẹmi ara rẹ naa, ki ọwọ ofin ma ba a tẹ fun ẹsun ipaniyan.