Coronavirus: Ìjọba Kwara ko fi ìgba kankan túra silẹ̀ dé Coronavirus

Ijọba ìpínlẹ̀ Kwara ni àwọn ti n gbaradi, ti gbogbo eto si ti wa nilẹ lati koju aarun gbẹ̀migbẹ̀mi Coronavirus àti Lassa Fever ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Bakan náà lo pé àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ ni láti tubọ tẹra mọ àṣà ìmọtótó lati dena ààrun aṣeku pani gbogbo to n bẹ nita.

Kọmisọna fún ètò ilera nipinlẹ Kwara, Dokita Raji Razaq lo kede ọ̀rọ̀ yiìí lásìkò to n ba àwọn oniroyin sọ̀rọ̀ nílu ilọrin lọ́sàn ọjọ Iṣẹgun.

O salaye pe gbogbo eto lo ti wa nilẹ láti koju ààrun náà nibi gbogb to ba ti ṣẹ́yọ.

Kọmisọna ni nítori akiyesi ìjọba ni àwọn ṣe ri àwọn mẹrindinlógun kan ti o ti ṣalabapade awọn ọmọ ilẹ Benin Republic mẹrin to ni Lassa Fever.

O ni àwọn mẹrẹrindinlogun náà to jẹ ọmo Naijiria ko tii fi ìbi kankan hàn pe wọ́n ni ààrun náà,nitori náà ki àwọn olùgbé ìpinlẹ Kwara lọ fi ọkan balẹ.

Kọmisọna ni sáàju ni ìjọba ti kede ka gbogbo ilé iwé la'ti kọ àṣà ọwọ́ fifọ nitori ààrun COVID-19

Razaq rọ àwọn olori ilé iwé lati ma fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mu ọ̀rọ̀ imọtótó.

Coronavirus: Ìrìnàjò gbẹ̀mí-gbẹ̀mí náà tún ti jà bíi ìjì wọ Saudi Arabia láti orí omi

Orilẹ-ede Saudi Arabia ti fidi rẹ mulẹ lọjọ Aje pe, arun coronavirus ti wọ orilẹ-ede naa, gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin orilẹ-ede naa ti kede rẹ.

Ileeṣẹ eto ilera ni orilẹ-ede Saudi salaye pe, ayẹwo fi aarun naa han lara ọmọ orilẹ-ede naa to ṣẹṣẹ de lati Iran, ẹni to gbe arun naa wọle.

Awọn alaṣẹ Saudi sọ pe, ọkunrin naa ko sọ sita pe orilẹ-ede Iran ni oun ti de lẹyin to wọle si Saudi Arabia, lati ori omi.

Ni kete ti wọn fidirẹmulẹ pe ọkunrin naa ni aarun yii, ni wọn ti ya a sọtọ.

Bakan naa ni wọn sọ pe, wọn ti ṣe ayẹwo fun gbogbo awọn to ti ni ibaṣepọ pẹlu ọkunrin naa lati igba to ti wọ Saudi, ati pe wọn yoo fi esi ayẹwo wọn sita to ba pari.

Minisita fun eto ilera, Tawfiq Al-Rabiah kede pe, awọn ko ri ẹnikẹni to ni aarun naa ninu awọn ọọdunrun din mẹwaa ti wọn ti kọkọ ro pe o ni i.

Al-Rabiah sọ pe, awọn n foju si gbogbo awọn to ba wọ orilẹ-ede naa lara, paapa awọn to ba wa lati eyikeyi awọn orilẹ-ede ti aarun naa ti n ba wọn finra.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji ni ijọba Saudi kede pe oun ti fi ofin de irinajo mimọ Umrah bayii, to fi mọ irinajo si ilẹ mimọ Mecca ati Medinah lati le deba itankalẹ aarun naa.

Ọjọ Aje ni iroyin kan jade pe aarun naa ti pa olori ẹsin kan ni Iran, Ayatollah Khamenei.