You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọwọ́ tẹ ajínigbé méjì tó fẹ́ ẹ́ já ọmọ gbà lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ l'Ondo
Ọrọ di da apada, a gbẹdọ, ka ma ri, nilu Erusu Akoko, nijọba ibilẹ Akoko North West, nipinlẹ Ondo lasiko ti awọn ajinigbe kan fẹ ẹ ji ọmọ gbe.
Iroyin fidirẹmulẹ pe awọn ajinigbe naa gbiyanju lati fi agidi àti ipá ja ọmọbinrin kekere kan gba lọwọ iya rẹ nilu naa.
Ati wi pe wọn gbe ọkọ kan wa to n duro lati gbe wọn lasiko ti wọn fẹ ja ọmọ naa gba.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, gẹgẹ bi iwe iroyin ori ayelujara Sunshine Truth ṣe jabọ, sọ pe awọn ri iya ọmọ naa to n jijakadi pẹlu awọn ajinigbe mejeeji naa, to si n pariwo ẹ gba mi o, ẹ gba mi o, ki awọn ara adugbo Aga Quaters nilu naa to o tu jade lati kapa awọn ajinigbe naa, ti ọwọ si tẹ wọn.
A gbọ wi pe niṣe ni awọn araalu ti inu n bi ja wọn si ihoho goloto, ti wọn si fẹ ẹ maa lu wọn ki ọba ilu naa, Ọba Sunday Mogaji, to o da si pe ki wọn o ma ṣe idajọ oju ẹsẹ fun wọn.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa lati ẹka wọn to wa ni ilu Okeagbe-Akoko wa si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ti wọn si mu wọn lọ si agọ wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Femi Joseph sọ fun BBC Yoruba pe wọn ti gbe awọn afurasi naa wa si ilu Akurẹ, ti ẹka ọtẹlẹmuyẹ si ti n wadii wọn.
Ọgbẹni Joseph tun sọ pe laipẹ ni wọn yoo gbe wọn lọ sile ẹjọ ti iwadii ba pari.