Stella Adadevoh tó dènà Ebola ní Nàìjíríà gba ìdálọ́lá lọ́wọ́ Ààrẹ Buhari

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi aami ẹyẹ akọni da oloogbe, Dokita Stella Ameyoh Adadevoh lọla fun ipa to ko lati dena itankalẹ aarun Ebola l'orilẹede Naijiria.

Buhari gbe ami ẹyẹ naa fun ọmọ oloogbe Adadevoh, Ọgbẹni Bankole Cardoso to sọju iya rẹ nibi eto naa.

Nibi ipade karundinlọgọta ti awọn aarẹ ati olori awọn orilẹede to wa ninu ajọ iṣọkan ẹkùn Iwọ oorun ilẹ Afrika, ECOWAs, ni Buhari ti fi ami ẹyẹ naa da a lọla.

Ninu ọrọ rẹ, Buhari gboriyin fun Dokita Adadevoh fun ifaraẹnijin ati iwa akọni to hu lati gbogun ti itankalẹ aarun Ebola ni Naijiria l'ọdun 2014.

Stella Adadevoh ni dokita to tọju ọmọ orilẹede Liberia, Patrick Sawyer, to gbe aisan Ebola wọ Naijiria lasiko naa, ti ko si gba ko fi ileewosan silẹ.

Bakan naa, oun lo kọkọ fi ọrọ Ebola ti oloogbe Sawyer gbe wọ Naijiria to ileeṣẹ eto ilera ijọba apapọ l'eti.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2014 ni Stella ku sọwọ oro aisan Ebola.

Ọmọ oloogbe fi iroyin naa si oju opo ayelujara Twitter rẹ, o si lo dupẹ lọwọ aarẹ Buhari.